Ojú ayé ló pọ̀ jùlọ fún àwọn gbajúmọ̀ orí ‘social Media’, gbèsè tí ọ̀pọ̀ wa ń sìn lábẹ́nú gọbọi – Ijoba Lande

Àkọlé fídíò, Ijoba Lande

Ganiyu Kẹhinde Morufu ti ọpọ n pe ni 'Ijọba Landẹ' ni ọpọ iṣoro lo n ba awọn eekan ti araalu n ri loju opo ayelujara kaakiri finra labẹ aṣọ ṣugbọn ti wọn ko le sọ sista.

O ni awọn miran to si fẹ sọrọ ko le e sọrọ nitori pe wn n ro ti yẹyẹ ati ẹsin ti awọn eeyan yoo fi wọn ṣe lori ayelujara ati loju aye paapaa.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, gbajumọ alawada naa ṣalaye gbogbo ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ to ṣẹ sii eyi to fi di awati fun ọpọlọpọ jọ.

Ijoba Lande sọ pe aye kii ba aladanwo ṣe ati pe gbese owo ori foonu ayelujara 'App' lo sọ oun di ẹni to n ronu lati pa ara rẹ.

O salaye pe ẹkọ ti oun kọ lori iṣẹlẹ naa ni pe ki oun ma gbẹkẹle eeyan mọ bikoṣe Olodumare nikan.