Ọmọ ọdún 16 tó gba àmì ẹ̀yẹ Guinness World Records nílùú Akure sọ ìrírí rẹ̀ fún BBC

Àkọlé fídíò, Ọmọ ọdun mẹrindinlogun to gba ami ẹyẹ agbaye ‘Guinness World Records’

Ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan to gba ami ẹyẹ agbaye ‘Guinness World Records,’ Ezekiel Gbenga, ti ṣalaye bo ṣe gba ami ẹyẹ ọhun.

Ezekiel gba ami ẹyẹ naa lẹyin to fo okun lori ẹsẹ kan fun igba to pọ ju laarin iṣẹju kan.

Gẹgẹ bii akọsilẹ Guinness World Records, igba 265 ni ọdọmọde naa fi okun fo lori ẹsẹkan laarin iṣẹju kan pere.

Eyii lo mu ki wọn fun ni iwe ẹri pe oun nikan lo tii ṣe irufẹ aṣeyọri bayii ni gbogbo agbaye lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.

“Inu idile mẹkunnu ni mo ti jade”

Gbenga ṣalaye pe ọdun 2021 ni oun bẹrẹ ere idaraya fifi okun fo, ati pe eredi ti oun fi yan ere naa laayo ni pe kii ṣe irufẹ ere idaraya to wọnpọ ni gbogbo agbaye.

O ni ọmọ idile atapata dide ni oun amọ eyii ko di oun lọwọ lati ṣe aṣeyọri nidi ere idaraya ti oun yan laayo.bb

Gbenga Ezekial Guinness world records

O sọ pe “Mo jade ni ẹbi mẹkunnu, awọn obi mi jẹ eeyan to n ta ọja... baba mi jẹ ‘panel beater.’”

“Ni ṣe ni Ezekiel maa n fo bii ẹyẹ”

Nigba ti olukọ ere idaraya ọmọ naa, Okando Joseph, n ba BBC Yoruba sọrọ, o ni ṣe ni ọmọde ọhun maa n fo bii ẹyẹ.

O ni “Ọmọ yẹn, o kan da bii ẹyẹ iji to n gbera ni.”

“Gbogbo nnkan ti Gbenga ba n ṣe, gbogbo ọkan rẹ lo maa n fi kọ ẹkọ nipa rẹ.”

Joseph ni ti ọmọ naa ba ti fi ọkan si nnkan to fẹ ṣe, ko si ohunkohun ti yoo di lọna lati ma ṣe aṣeyọri ninu nnkan ọhun.

Gbenga Ezekial Guinness world records

“O yẹ ki a lọ fun idije agbaye nilẹ Amẹrika amọ ko si iranlọwọ lati ọdọ ijọba”

Olukọ Gbenga ṣalaye siwaju si pe lẹyin ti ọmọ naa bẹrẹ ere idaraya ọhun to si n ṣe daadaa, awọn gbe igbesẹ lati tẹkọ leti lọ soke okun fun idije agbaye kan amọ ko bọ so.

O ni kii ṣe ami ẹyẹ agbaye Guinness World Records yẹn gan lo wa lọkan oun fun ọmọ naa nibẹrẹ, amọ nnkankan lo ṣokunfa rẹ.

Gbenga Ezekial Guinness world records

“Kii ṣe pe nnkan to wa lọkan wa lakọkọ niyẹn, o kan jẹ wipe lọdun to kọja, o yẹ ki wọn lọ si idije ife ẹyẹ agbaye kan niluu North Carolina lorilẹ-de Amẹrika.”

“Nigba yẹn emi gan ti gbaradi fun wọn, ṣugbọn a ko ri iranlọwọ lati ọwọ ijọba... a ko ri owo lati lọ.”

Olukọ naa ni iṣẹlẹ ọhun ba Gbenga atawọn akẹgbẹ ninu jẹ pupọ, eyii lo mu ki oun gbiyanju ki ọmọ naa le gba ami ẹyẹ agbaye Guinness World Records lati fi tu wọn ninu.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ifọrọwerọ naa.