Subsidy removal in Nigeria: Kí ni ìtumọ̀ ‘Subsidy’ àti pé kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tí ìjọba bá yọ ‘Subsidy?’

Aworan ile epo kan

Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti kede pe ijọba oun yoo yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro 'Subsidy' ni kete to gba ọpa aṣẹ .

Lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ fun igba akọkọ gẹgẹ bii Aarẹ Naijiiriani gbagede Eagles Square niluu Abuja, Tinubu ni "Ko si subsidy mọ."

O fi kun ko si ipese fun afikun owo epo naa ninu eto iṣuna ọdun yii.

Ẹwẹ, ọpọ awọn araalu lo ti n bere pe ki ni 'subsidy' gan an?

Ati pe ki ni yoo ṣẹlẹ ti opin ba de 'subsidy' ni Naijiria.

Aworan ibudo ipọnpo kan

Oríṣun àwòrán, Nnpc

Ki ni itumọ 'subsidy?'

'Subsidy' n tumọ si igba ti ijọba ba n san lara owo to yẹ ki awọn araalu maa san fun nnkankan, bii ile gbigbe, epo bẹntiro, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ni Naijiria, ijọba apapọ lo n san awọn ida kan lara owo epo bẹntiro ti awọn araalu n ra lawọn ile epo, bi bẹẹ kọ, o yẹ ki jala epo bẹntiro kan wọn ju iye ti awọn araalu n ra a lọ.

Àkọlé fídíò, Ṣe lootọ;Njẹ́ o ní nkán tí èèyàn lè ṣe tí kò bá fẹ bí ọmọ àfín

Fun apẹrẹ, ti awọn araalu ba n ra jala epo kan ni ₦‎185, o n tumọ si pe ijọba apapọ ti san iye kan lara iye gan to yẹ ki owo epo naa gan jẹ ni san an. O le jẹ ₦‎185 to jẹ ilaji, ju bẹẹ lọ tabi ko kere si iye yii, ṣaaju ki epo naa to de ile epo ọhun.

Iyẹn ni pe iye to yẹ ki wọn maa ta jala epo ni Naijiria lai si 'subsidy' nibẹ lee to ₦‎370 tabi ju bẹẹ lo gan.

Aworan ibudo ikepopamọsi kan

Oríṣun àwòrán, Nnpc

Ki ni itumọ pe ijọba yọ 'subsidy?'

Ni kete ti ijọba ba ti fopin si 'subsidy,' iyẹn ni pe ijọba yoo dẹkun ati maa san owo to n san fun awọn alagbata epo ṣaaju ki wọn to maa pin kaakiri awọn ile epo.

Lai fa ọrọ gun, iye ti awọn araalu yoo maa ra epo yoo fo lati ₦‎185 si ₦‎370 tabi ju bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Ohun tí ojú àgbà rí tí ojú àgbà fi jìn, bí ọmọdé bá rí i ó ṣeéṣe kí ojú náà fọ́ pátápátá.

Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ba ti yọ 'subsidy' tan?

Yiyọ owo iranwọ ori epo n tumọ si pe awọn araalu yoo maa ra epo bẹntiro ni iye owo ti wọn n ra a tẹlẹ lọ, tabi ki a kuku ni wọn yoo maa ra epo ni ọwọngogo.

Ni ida keji, nnkan yoo wọn gogo, koda epo ati owo ọkọ ti bẹrẹ si n wọn lawọn ipinlẹ kan bayii bii ipinlẹ Eko, bẹẹ ni ọpọ ero lo ti n to sile epo lati tete ra epo pamọ.

Àkọlé fídíò, Ka nipa awọn eewọ Iwoye Ketu eyi to rọ mọ alubọsa,aburanda ati ẹlẹ́dẹ̀

Yatọ si epo ti yoo wọn, owo ọkọ, owo ounjẹ, owo ile, owo asọ, atawọn nnkan mii ni yoo wọn nitori ori ọwọngogo epo ni awọn eeyan yoo maa di ẹbi ọrọ naa le.

Amọ ṣa, ijọba ti sọ pe yiyọ owo iranwọ ori epo naa yoo ṣeranlọwọ fun ọrọ aje Naijiria, bẹẹ si ni ijọba yoo lo owo naa lati fi sẹ awọn ohun meremere atawọn ohun amayedẹrun saarin ilu.

Wayi o, ero awọn ọmọ Naijiria ṣ'ọtọtọ lori igbesẹ ijọba Tinubu lati yọ 'subsidy,' bi awọn kan ṣe faramọ igbesẹ naa lawọn mii n sọ pe ọpalamba iya ni yoo jẹ awọn ọmọ Naijiria.

Aworan ibudo ipọnpo kan

Oríṣun àwòrán, Nnpc

Ṣe aisi ibudo ipọnpo to n ṣiṣẹ ni Naijiria lo fa Subsisy sisan ni?

Ọpọ lo n sọ pe nitori pe ko si eyikeyi ibudo ifọpo (refinery) kankan to n ṣiṣẹ ni Naijiria eyi to mu ki a maa ko epo rbi lọ si ilẹ okeere, fi ra afọmọ epo bii bẹntiro, disu, kerosini ati bẹẹ lọ lo fa sisan owo iranwọ ori epo.

Irọ to jina si otitọ ni eyi.

Lasiko ti awọn ibudo ifọpo wọnyi n ṣiṣẹ ni ijọba ti n san owo subsidy yii. Iyatọ to wa nibẹ kan ni wi pe, nigba naa, ileeṣẹ epo rọbi Naijiria to n ṣe akoso awọn ibudo ifọpo rọbi naa ni wọn n san an fun.

Iyatọ to wa nibẹ lasiko yii to jẹ pe ilẹ okeere la ti n ra epo wale ni wi pe iye owo naa yoo pọ sii

Àkọlé fídíò, TolaSex style and danger in pregnancy: Irú sítàílì ìbálòpọ̀ wo ló n jẹ́ kí oyún tètè dúró?

Nitori pe awọn oniṣowo epo to n ra epo wọle yoo ṣiro owo ti wọn fi ra epo ni ilẹ okeere, owo ọkọ ojuomi alagba nla ti wọn fi ko o wa si Naijiria pẹlu owo ibudo ikepopamọ si (Jetty) ti wọn yoo koo si nigba to ba de Naijiria.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra

Gbogbo eyi ni wọn yoo ṣiro pọ lati fi ṣe odinwọn iye ti wọn yoo ta jala epo kan. Ẹ maa gbagbe pe gẹgẹ bi oniṣowo, awọn naa a fi ere si ori rẹ. Ilaji iye ti wọn ba wa pe owo epo lẹyin ti wọn ba ṣiro gbogbo nnkan wọnyii ni ijba yoo ti wa san iye idan kan lara rẹ.