Bí èèyàn fi màlúù ránṣẹ́ tí wọ́n bá sè é yóò kan, mọ́tò ni kí ẹ rà fún mi báyìí – Iya Gbonkan

Iya Gbonkan

Oríṣun àwòrán, others

Gbajumọ oṣere tiata, Arabinrin Margareth Bandele Ọlayinka, ti ọpọ mọ si iya Gbonkan ti fi ohun sita pe ki awọn ololufẹ oun ra ọkọ fun oun lati maa fi ṣe ẹsẹ rin.

Ninu fidio kan to n lọ kaakiri lori ayelujara ni agba oṣere yii ti rawọ ẹbẹ yii.

Iya Gbonkan ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun pe o ṣeeṣe ki awọn ti ko ran oun lọwọ nigba ti oun wa laye lee jade maa fi maluu ranṣẹ fun ayẹyẹ isinku oun nigba ti oun ba papoda tan.

“Ki lo wa de ti ẹ n wo mi niran. Haha, ẹsẹ ni mo fi n rin. Mo n gan mọto kaakiri ni. Ṣe ko yẹ ki iru mi yi ni ẹsẹ mẹrin lati fi maa rin. Nigba ti eeyan ba wa ku tan ẹ o wa maa fi maluu ranṣẹ.”

Eekan oṣere tiata naa tun tẹ siwaju lati sọ pe oun ko fẹ ki ẹnikẹni wa maa ṣe pẹpẹfuru kankan lẹyin iku oun lai jẹ wi pe iru ẹni bẹẹ ṣe iranwọ gbogbo to ba tọ fun oun nigba ti oun ṣi wa laye.

“Bi eeyan ba fi maluu ranṣẹ (nigba isinku mi) bi wọn ba se e yoo kan. Ẹ ṣe mi loore. Mo n fẹ mọto.”

Iya Gbọnkan wa rawọ ẹbẹ si awọn ololufẹ rẹ lati ra mọto fun oun nigba ti oun ṣi wa laye bayii, ‘ko ma baa la ti ẹgba lọ’.