Owó oṣù: Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun daṣẹ́ sílẹ̀

Aworan

Niṣe lọrọ naa dabi awada laarọ Ọjọbọ tii ṣe Tọside, nigba ti awọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun labẹ aburada ẹgbẹ ti wọn pe ni Parliamentary Staff Association of Nigeria (PASAN) daṣẹ silẹ lojiji, ti wọn si kede pe idaṣẹ-silẹ onikilọ l'awọn n lọ.

Ọjọ mẹta gbako ni awọn oṣiṣẹ naa sọ pe awọn yoo fi daṣẹ silẹ lati kilọ fun awọn alakoso ile igbimọ aṣofin naa ti wọn kọ lati ṣagbeyẹwo owo oṣu wọn.

Nibi ifẹhonuhan naa ni awọn oṣiṣẹ yii ti n rawọ ẹbẹ si Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ naa lati dide si ọrọ yii, ko too to ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023.

A gbọ pe awọn oṣiṣẹ PASAN yii n beere fun owo oṣu tuntun to lọ nibamu pẹlu ofin, eyi ti wọn pe ni Consolidated Legislative Salary Structure (CONLESS).

Ninu lẹta ti akọwe agba ẹgbẹ naa lapapọ, Kọmureedi Awobifa Hammẹd kọ lọjọ kẹsan, oṣu karun-un, ọdun yii naa lo tun ti jẹ ko di mimọ pe awọn n fẹ ẹkunrẹrẹ owo oṣu ni ibamu pẹlu ofin ati agbekalẹ,

Eyi ti wọn ṣe lọdun 2018, iyẹn Ogun State House of Assembly Service Commission Law, 2018 and Statutory Office (State Emolument) Amendment 2018.

Aworan
Aworan
Aworan

Kọmureedi Awobifa Hammẹd lakoko to n fi ẹdun ọkan rẹ han sọ pe latigba t'awọn ti fi lẹta wọn ranṣẹ s'awọn alakoso mẹta ọtọọtọ n'ipinlẹ Ogun,

O ṣeni laanu pe wọn ko gbọ esi titi di asiko yii.

O ni agbọpa, to tun jẹ olori awọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin naa ati igbakeji rẹ, to fi mọ akọwe ni wọn n gba owo wọn bo ti tọ, ati bo ti yẹ lẹkunrẹrẹ,

pẹlu awọn ajẹmọnu, to si ni ko boju mu to lati maa fi ẹtọ awọn yooku dun wọn.

Awọn oṣiṣẹ naa wa n rawọ ẹbẹ si Gomina Dapọ Abiọdun lati gbe igbesẹ lori ohun ti wọn n beere fun yii, ko too to ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un,

ko ma ba a jẹ pe awọn yoo gbe igbesẹ miran labẹ ofin.