Èlò ní ''Celebrity'' n gbà tí ẹ fi ní kí n sàn owó orí N18m - Iyabo Ojo sí ìjọba Èkó

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/Instagram
Gbajugbaja oṣerebinrin to tun jẹ ilumọọka apanilẹrin lori ayelujara, Iyabo Ojo Fespris, ti n fesi lori owo ori ti ijọba ipinlẹ Eko fun un ni gbedeke ọjọ meje lati san si akoto ijọba.
Iyabo ni inu n bi oun pẹlu aduru owo ti ijọba sọ pe oun jẹ lowo ori yii.
O ni nigba toun beere idi ti owo naa fi pọ to bayii alaye ti wọn ṣe ni pe awọn ni k'oun san owo naa nitori pe oun jẹ ''gbajumọ'' tabi ''celebrity''.
Atupalẹ iye owo ti BBC ri ka ninu iwe ti ajọ to n gba owo ori fi ranṣẹ si Iyabo Ojo fihan pe N18,640,092.00 ni owo ori to jẹ ijọba.
Iwe yi ṣalaye pe o jẹ gbese N7,376,000.00 lọdun 2022 to si ni gbese N11,264,092 to wa nilẹ lọdun 2021.
Gbedeke ọjọ meje ni ijọba lawọn fun lati fi wa san owo yii bi bẹẹ kọ yoo foju wina ofin.

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo
''Mi o ṣẹṣẹ maa san owo ori. Mo n san owo ori lori ile ti mo ra ni san diẹ diẹ. ''
Loju opo rẹ ni Instagram, Iyabo Ojo ṣe fidio kan sita nibi to ti ṣafihan awọn iwe kan to ni o jẹ ẹri owo ori ti oun san fun ile ati iṣẹ rẹ.
O ni oun ati alamojuto eto owo ori oun ti kan si awọn alaṣẹ ṣugbọn wọn ko gbọ alaye ti oun ṣe fun wọn.
O beere pe ''elo gaan lowo ti mo n ri nidi ere sinima debi pe wọn yoo wa ni ki n san owo ori to le ni miliọnu meje Naira?''
Iyabo ni kii ṣe pe oun ko ni san owo tabi pe oun ko fẹ san owo ori ṣugbọn o ni ijọba ni lati ṣe alaye bi wọn ṣe ṣiro aduru owo ori yii le oun lori.
Ọna kan ti ọrọ owo ori yii tun gba yọ niṣe pẹlu esi kan ti Iyabo fọ wi pe oun lẹtọ lati ṣe atilẹyin fun ẹnikẹni to ba wu u.
O fọ esi yi ni idahun si ibeere tawọn kan beere loju opo rẹ pe boya nitori ti ko ṣe atilẹyin fun ijọba to wọle ni Eko ni wọn fi da aduru owo ori yi le e lori.
Ninu idahun rẹ, Iyabo Ojo sọ pe ''mo lẹtọ lati ṣe atilẹyin ẹnikẹni to ba wu mi'
Ko jẹ tuntun pe Iyabo Ojo ṣe fidio bẹẹ lo si sọ ọrọ pe oun ko le ṣatilẹyin fun Bola Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aarẹ.
O sọ pe lootọ ni Tinubu ṣe atilẹyin lọna kan tabi omiran fun oun ṣugbọn ọrọ oṣelu ati yiyan ẹni to yẹ si ipo yatọ si ka fi ti ajọṣepọ ṣe.
Ọrọ yii mu iyapa wa laarin oun ati awọn akẹgbẹ rẹ oṣere mii to ni o hu iwa aimoore.
Iyabo Ojo nitori eleyi wa soko ọrọ si awọn akẹgbẹ rẹ kan to ni wọn kọ lati wa sibi awọn ode rẹ nitori pe ero wọn ko papọ nidi ẹni ti wọn ṣatilẹyin fun lagbo oṣelu.
"Mo lẹtọ lati ṣe atilẹyin ẹnikẹni to ba wu mi"
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Iyabo Ojo nikan kọ ni gbajumọ ti wọn n beere owo ori lọwọ rẹ
Ni ọjọ Aje ni ijọba ipinlẹ Eko fi ẹsun onigun mejila kan lelẹ niwaju ile ẹjọ giga eyi ti wọn fi kan gbajumọ aṣelelọsọ, Ehizogie Ogbebor.
Ninu ẹsun yii, wọn ni o kọ lati fi ẹri han pe o san owo ori rẹ.
Agbẹjọro ijọba A.I Alli sọ pe Ehizogie to tun jẹ gbajumọ ori ayelujara Instagram kọ lati san owo ori rẹ lati ọdun 2014 titi di asiko yii.
Gẹgẹ bi Alli ṣe sọ, o ni eeyan to tọ si ko san owo ori ni Ogbebor jẹ ṣugbọn o kọ lati san an.
O ni iwa yii tako ofin orileede Naijiria to de sisan owo ori.

Oríṣun àwòrán, ceosayavethinteriors_and_hotel












