Wọ́n ṣìmí gbọ́ ni, n kò le ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Tinubu - Bode George

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Igbakeji alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bode Geroge ti ni irọ ni iroyin to ja kiri pe oun setan lati sisẹ pọ pẹlu Aarẹ Bola Tinubu ti wọn ba kesi oun fun iranlọwọ.

Oloye ni ileeṣẹ iroyin to gbe iroyin naa jade si oun gbọ ni ati pe wọn ko si nibẹ lasiko ti oun pe ipade pẹlu awọn akọroyin nibi to sọrọ lori nnkan ti oun yoo se ti Aarẹ Tinubu ba kesi oun.

O sọ eleyi lasiko to n kopa ninu ifọrọwerọ kan to se lori ileese momaworan kan lowurọ ọjọ Aje.

O ni , “Nigba ti wọn bi mi pe kini ma se ti Tinubu ba pe mi, mo si sọ fun wọn pe ti Tinubi ma pe, ma gba adura fun orilẹede Naijiria.

“N ko ki se ọmọ kekere . Ajagun fẹyinti ni mi. Ki Tinubu fẹ pe fun. A ko si ninu ẹgbẹ oṣelu kana.

“To ba ni Hello Oloye, ẹ kar\i, ma fesi pe Ẹkarọ Aarẹ , iyẹn ti ileẹjọ ko ti yi ipiinu wọn pada nitori a si wa ni ileẹjọ bayii.

“Nigba ti Baba Olusi cwa bami sọrọ gan an, pe ki lọ ki Tinubu ku orire, mo ni rara pe n ko le se bẹ.

“Nnkan ti wọn se ni ko ye mi, n ko ni nnkan pọ pẹlu ọmọkunrin yii, erongba wa kan yatọ ni”

Ti a ko ba gbagbe, Iroyin n jakiri pe Oloye Bode George ti setan lati sisẹ pọ pẹlu Aarẹ Tinubu ti o ba kesi.