Seyi Makinde ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn adarí tuntun fún ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò

Seyi Makinde ati Tomiwa Omolewa

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gomina ipinẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti ṣe ipade pẹlu awọn adari tuntun to ṣẹṣẹ yan fun ẹgbẹ awọn lọkọ ero PMS lalẹ ọjọ Aje.

Iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ fi idi rẹ mulẹ pe Ọgbẹni Tọmiwa Ọmọlẹwa to jẹ alaga tuntun fun ẹgbẹ naa ko awọn ọmọ igbimọ akoso tuntun naa lọ si ile gomina Makinde to wa lagbegbe Ikọlaba ni ilu Ibadan, ni alẹ ọjọ Aje.

Lara awọn to ko sodi lọ ni:

Kasali Ajisafẹ Lawal to jẹ akọwe, Tajudeen Jimoh, to jẹ igbakeji alaga; Kamardeen Idowu, to jẹ akapo; Tirimisiyu Olowoposi, Abass Amolese, ati Hamidu Mustapha Were.

A ko tii le fi idi rẹ mulẹ, ohun gan ti wọn sọ pato nibẹ ṣugbọn awọn to sun mọ igun mejeeji sọ pe ọrọ lori ibaṣepọ alaafia laarin igun gbogbo to wa ninu ẹgbẹ awakọ ero ni ipinlẹ Oyo ni wọn jiroro le lori.

Makinde yan alága ẹgbẹ́ awakọ̀ PMS tuntun láti rọ́pò Auxiliary l'Ọ̀yọ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ijọba ipinlẹ Oyo labẹ isakoso Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti kede Ahaji Oluwatomiwa Omolewa, akọweẹgbẹ igbimọ to n se akoso awọn gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo, PMS tẹlẹ gẹgẹ bi alaga tuntun fun ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo.

Bakan naa ni ijọba Oyo kede pe Alhaji Kasali Ajisafe Lawal ti ópọ mọ si Baba Bola yoo si jẹ akọwe ẹgbẹ tuntun.

Eyi lo jẹyọ ninu atẹjade ti agbẹnusọ gomina lori iroyin, Sulamion Olarenwaju fi ransẹ si awọn akọroyin lọjọ aiku.

Atẹjade naa ni lẹyin ti ijọba se ipade pẹlu awọn igbimọ ẹgbẹ igbimọ to n se akoso awọn gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo, PMS ni wọn yan alaga tuntun ọhun.

Atẹjade naa ni; “ Ijọba ipinlẹ Oyo n fi asiko yii kede Alhaji Oluwatomiwa Omolewa, akọwe ẹgbẹ tẹlẹ gẹgẹ bi alaga tuntun fun ẹgbẹ PMS nipinlẹ Oyo.

“Alhaji Kasali Ajisafe Lawal ti ọpọ mọ si Baba Bola yoo si jẹ akọwe ẹgbẹ naa

“Eyi ni atunse ti ijọba fẹ se si ẹgbẹ awọn ibudoko ọkọ nipinlẹ Oyo.”

Ki ni o sẹlẹ tẹlẹ?

Ọsẹ to kọja ni akanṣe ipade apero waye e lati wa ojuto si iṣoro to n koju ajọ to n ṣe amojuto ibudokọ n'ipinlẹ Ọyọ, PMS ni gbọngan nla 'House of Chiefs’ to n bẹ ninu ọgba ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ ni agbegbe Agodi nilu Ibadan.

Alaga ipejọpọ naa, Ọjọgbọn Duro Adeleke ti o ba awọn eeyan sọrọ nibi ipejọpọ naa ṣe alaye wi pe eeyan maa n tan, ṣugbọn itan kii tan.

O tẹsiwaju wi pe ko yẹ ki iranti ẹnikẹni jẹ baalẹ ṣa ada-ṣa ada tabi iwa ipanle mii.

Ti a ko ba gbagbe, lẹyin iburawọlw Gomina Seyi Makinde ni ijọba fi ẹyinkunle ọwọ ju we ile fun alaga tẹlẹ, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ mọ si Auxilary

Ọrọ naa lo si n fa ọpọ ikayasoke laarin awọn eeyan ipinlẹ naa, paapaa julọ ilu Ibadan.

Kìí ṣe ilé mi ni wọ́n ti bá àwọn ìbọn àti àwọn ohun ìjà olóró tí ọlọ́pàá kó kalẹ̀ - Auxiliary

Aworan

Alaga akoso paaki tẹlẹ nipinlẹ Oyo Mukaila Lamidi, ẹni ti ọpọ mọ si Auxillary ti ni gbogbo ohun ti awọn ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo safihan gẹgẹ bi ohun ija oloro ti wọn ko ni ile rẹ ni ko ki se tirẹ rara, ti wọn ko si le kede pe wọn n wa nitori ko tapa sofin tabi wuwa janduku kankan.

Ti a ko ba gbagbe, lati bi ọsẹ kan sẹyin ni ija laarin ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Oyo ti bẹrẹ lẹyin ti Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kede pe ki awọn alakoso paaki nipinlẹ Oyo lọ rọkun ni ilẹ.

Awọn ọlọpaa ni eeyan mejidinlọgọrin ni awọn ko nile 'Auxiliary' lasiko ti wọn ya wọ ibẹ.

Bakan naa ni wọn ba onde, ibọn ati ohun ija ija loriṣirisi ninu ile naa.

Iroyin ni bi o tilẹ jẹ pe Auxiliary ti na papa bora, ẹmi eeyan kan ba iṣẹlẹ lọ lasiko ti wọn kọju ija si awọn agbofinro.

Auxillary, ẹni to sọrọ lori eto kan lori redio ni oun ko fi igba kankan tako asẹ Gomina Seyi Makinde nitori olore oun ni.

“Nnkan to sẹlẹ ni pe Otunba Seyi pe mi pe awọn ọmọ ẹghẹ oselu APC ti wọn ti kuro ninu ẹgbẹ omi moto fun bi ọdun mẹdogun fẹ pada, ti gbogbo wa yoo si dapọ

“Wọn ni awọn yoo mu awọn ọmọ lẹyin mi kuro, ti mo si ni ko le sese rara, nitori mo mọ bi awọn amugbalẹyin se jiya lori ẹgbẹ naa."

"Pe wọn kede pe wọn wa mi ki se temi rara"

Auxillary salaye pe Gomina Seyi Makinde lo ni isakoso ipinlẹ Oyo, to si le dari rẹ bi o ṣe fẹ si, ti oun ko si tako asẹ Gomina ni igba kankan.

o ni bi ileeṣẹ ọlọpaa se kede pe wọn wa oun ni ko boju mu, ti ko dẹ ki n se ti toun rara nitori oun koja tabi fa wahala.

“Ko si nnkan ti ọga se ti mo tako nitori baba ọmọ lo lọmọ .

“Sugbọn bi awọn Ọlọpaa se kede pe awọn wa mi yii ni ko ki se temi rara nitori pe n ko ja , n ko se nkankan

“Gbogbo awọn Ọlọpaa ti wọn lọ ko ibọn jọ yẹn, ẹ jọr, jagunjagun ki se ẹgbẹ ọlọdẹ rara.

“Se ti n ba tiẹ wa ni irufẹ ibọn naa to to ba yẹn ni ile mi, ma wa ko si ninu ile mi ti mo n gbe.N ko ki se omugọ rara.”

“Oloore mi ni Gomina Seyi Makinde“

Auxillary ni gbogbo nnkan ti Gomina Seyi Makinde ba fọwọ si ni oun naa setan lati tẹle, ko da oun faramọ tiwọn ba yọ oun gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ onimọto nipinlẹ.

“Gbogbo nnkan ti Gomina Seyi Makinde ba ti se ni mo se, n ko le ba ijọba ja rara.

“Nnkan ti Gomina ba ti fẹ ni mo fẹ, ti wọn ba ni mo wa nibẹ deede, ti wọn ba ni rara, deede ni lara mi.

“Sugbọn n ko si erongba lati kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lialia nitori olore mi ni Gomina Seyi Makinde.”