Dúkìá Ààrẹ Buhari kò lè síi nígbà tó wà lórí oyè - Garba Shehu

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iroyin ti handle wípé ọrọ ati dukia ti Ààrẹ ana ti orileede Naijiria ko pọ ju ohun to wa nibẹ lọ lasiko to wa lori aleefa gẹgẹ bi Ààrẹ Naijiria fun akoko saa ọdun mẹjọ to lo.

Agbenusọ Ààrẹ ana, Garba Shehu lo fi alaye naa síta loju opo Twitter rẹ lọjọ Abameta wipe Ààrẹ tẹ́lẹ̀ fi àkọsílẹ̀ dukia rẹ ṣọwọ si Ileeṣẹ to n ri si ihuwasi ati dukia awọn oṣiṣẹ ijoba (Code of Conduct Bureau) ni ibamu pẹlu abala ikẹfa ti ìwé òfin Naijiria.

"Lónìí Ileeṣẹ to n ri si ihuwasi ati dukia awọn oṣiṣẹ ìjọba ti fesi pe awọn ti gba iwe àkọsílẹ̀ naa ti Ààrẹ ana fi ṣọwọ si wọn eyi to si ni aworan iwe owo nina".

Atẹjiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Garba Shehu/Twitter

Agbenusọ Ààrẹ tẹ́lẹ̀ yii tun ṣàlàyé pe Buhari ko ṣe afikun apo isuna tuntun mii kun eyi to ni tẹ́lẹ̀ ni banki Union to n lo eyi to wa nilu Kaduna.

"Buhari ko ya owo kankan bẹẹ si ni ko jẹ gbèsè kankan," Shehu sọ bẹẹ.

"Iye ẹranko to wa ninu oko rẹ dinku díẹ̀ latari iye to fi ṣe ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ fáwọn eniyan laarin ọdun mẹrin sẹ́yìn."

Buhari to ṣẹ̀ṣẹ̀ gbe eku ida iṣejoba le ààre Bola Tinubu lọwọ lọjọ kọkàndinlogon Oṣù Kàrún ọdun 2023 lẹyin ọdún meje lori alefa ti lọ fi ẹyin ti si ilu ibi rẹ, Dara ni Ìpínlẹ̀ Katsina bayii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post