Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun ìjọ CCC lẹ́yìn tí alágbàṣe jábọ́ sínú sọ́kàwee l'Eko

Ilé ìjọsìn

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ọ̀dọ́ ti inu n bi dana sun ìjọ Celestial kan to wa ni Badore, Ajah nipinlẹ Eko.

Iroyin sọ pe iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti arakunrin kan ṣubú sinu sọkawe ile ijọsin naa ni oru ọjọ Satide, ọjọ kẹta, oṣù Karùn-ún, ọdún 2023.

Oloogbe naa ti wọn pe orúkọ rẹ ni Dogo, ni awọn alaṣẹ ìjọ naa, CCC Overcomers Parish, Oke Ira nla, gbà pe ko ba wọn ko sọkawe naa ni alẹ́ ọjọ́ Ẹti.

Àwọn ti iṣẹlẹ naa ṣojú wọn sọ pé ni nnkan bi aago kan òru, ni ọmọ ìjọ naa to n ṣe amojuto bi Dogo ṣe n ṣiṣẹ́ rẹ, ṣe akiyesi pe oun ko ri i mọ.

"Níbi ti wọn ti n wa a, ni wọn ti ri pe o ti jabọ sinu sọkawe naa.

Bi iroyin iku Dogo ṣe jade si adugbo, ni àwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ si sọ pe wọn fi ṣe etutu ninu ṣọ́ọ̀ṣì naa ni.

Àwọn iroyin kan ti ẹ sọ pe wọn ti gé awọn ẹ̀yà ara rẹ kan ki wọn o to gbe oku rẹ jade.

Iroyin yii lo bi àwọn ọ̀dọ́ to jẹ ẹ̀yà kan naa pẹlu Dogo nínú, ti wọn fi dana sun ile ijọsin naa.

Kini awon alase ijo CCC sọ?

Sugbọn ninu atẹjade kan ti àwọn alaṣẹ ìjọ CCC fi sita, wọn ni irọ ni iroyin naa.

Wọn sọ ninu atẹjade naa ti oludari ikede, Sup. Evangelist Kayode Ajala fi sita pe, lootọ ni awọn alaṣẹ ìjọ Cele ti iṣẹlẹ ti waye, gba Dogo lati kó sọkawe to kún.

"Ọlọkada ni Dogo ni agbegbe naa, o si tun ma n ba awọn ara adugbo ko sọkawe wọn lati ọpọlọpọ ọdun.

" Ẹsẹ̀ rẹ ló yọ̀ to fi jabọ sinu sọkawe to n ko. Ni kia si ni olùsọ Agutan to n mojuto, gbiyanju lati fa a jáde, àmọ́ oun naa ko si inu sọkawe.

"Ariwo fun iranlọwọ ni àwọn ọmọ ìjọ to n ṣe ìṣọ́-òru ibẹrẹ oṣù tuntun gbọ́, ti wọn fi sa jáde."

Kayode Ajala sọ pe wọn ri awọn mejeeji fa jáde, sugbọn oku ni wọn ba Dogo, ti olùsọ àgùntàn naa si ti dákú rangbandan.

O ni olùsọ naa ṣi wa ni ileewosan nitori ara rẹ ko tii balẹ̀ rara.

Bákan naa lo sọ pe wọn ti gbe oku Dogo fun àwọn ẹbí rẹ̀, ti ileeṣẹ ọlọpaa si fìdírẹ múlẹ̀ pe ẹ̀yà ara rẹ kankan ko di awati.

Iwe iroyin Punch jábọ̀ pé ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọwọ́ ko tii tẹ afurasí kankan lára awọn to dana sun ile ijọsin naa.