Joke Muyiwa: Ẹ má wòó pé tí ẹ bá ti rí òṣèré tíátà, ẹ ti rí olówó

Àkọlé fídíò, Ifọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú gbajúgbajà òsèré tíátà, Joke Muyiwa

Gbajugbaja oṣere tiata, Joke Muyiwa ni o ṣeni laanu pe oju olowo ni pupọ awọn ololufẹ osere tiata fi ma n wo wọn.

Joke Muyiwa sọrọ yìí lasiko to kopa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ BBC News Yoruba.

O ni ti dandan ki awọn ololufẹ ere tiata ma ba wọn fọwọsowọpọ, ki wọn si maa a dede rope tí wọn ti salabapade osere tiata nitori isẹ ni onikaluku n se.

"Tootọ ere ni a n ṣe sugbọn isẹ nla ni.

"Tí ọpọlọpọ ba ti rí wa bayi, wọn gbagbọ pe owo ti de.

"Awa naa ni mọlẹbi, ti a ba sisẹ owo, ṣe wọn ko fẹ ka bọ mọlẹbi wa ni.

"Ẹ wa fẹ ka ma fun yìn lowo ni ikorita kọọkan, ki ẹ maa sọpe ẹyin ẹ n wo fimu wa.

"Owo ni a fi ṣe awọn isẹ wọnyi, nigba ti a ba ha owo tan, kini ka fi bọ mọlẹbi wa.

"Ko si iẹ ti eeyan ko ti le sisẹ aṣẹwo"

Joke Muyiwa salaye pe bí isẹ sinima ṣe jọ mọ sisẹ pọ pẹlu ọkùnrin ko kun to lati se isẹ aṣẹwo sugbọn ohun to hu onikaluku lo le ṣe.

O tẹsiwaju pe sisẹ isẹ aṣẹwo wọnyi lori sinima ko tun sì pe awọn ṣe ìsẹ loju aye.

"Tí olùdarí mi ba ni kí ṣe aṣẹwo agbalagba, ma ṣe, ko tun mọ sì pe aṣẹwo ni mí.

"Ti n ba pinnu pe lati se isẹ ninu sinima mi, ma ṣe, hookup ìyẹn ko tun mọ si pe mo n se iwa idọti tabi ki ẹnikẹ́ni ṣe ayafi to ba wu wọn lati se.

"Emi o ri nnkan to jọ mọ pe wọn ṣe isẹ aṣẹwo ninu ere sise, isẹ ti mo ti n se fun ọdun mẹtalelogoji nìyẹn"

Ekunrere wa ninu fidio to wa loke yii.