Àwọn ẹ̀ṣọ́ elétò ààbò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ kára-kára ju titẹ́lẹ̀ lọ - Ààrẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Tinubu/Facebook
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti ni o pọn dandan ki awọn ẹṣọ alaabọ lorilẹede Naijiria ṣiṣẹ karakara ju ti tẹlẹ lọ.
Tinubu sọ eyi lasiko to n ṣe ipade pẹlu awọn adari ẹṣọ alaabo lorilẹede Naijiria ni ilu Abuja.
Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ijiroro naa, olubadanmọran fun aarẹ lori eto aabo, Babagana Monguno ni aarẹ ti sọ fun wọn pe oun ko ni gba ẹnikẹni laaye lati doju ijọba bolẹ.
O ni orilẹede Naijiria ko gbọdọ jo ajorẹyin, ti a ba ṣe akawe rẹ pẹlu awọn orilẹede to ku.
Bakan naa lo ni ibaṣepọ to dan mọọran gbọdọ wa laarin awọn ẹka ẹṣọ alaabo ni Naijiria lati fi opin si eto aabo to mẹhẹ.
Aarẹ Tinubu ti wọn burawọle fun ni Ọjọ Aje ṣeleri lati fopin si eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter








