Asáko wá ti padà wálé; A ṣetán láti yánjú aáwọ̀ láàrín ara wa –Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Twitter
Gomina ipinlẹ Oyo, Amojuẹrọ Seyi Makinde ti fi ọrọ sita gẹgẹ bo ṣe ke si awọn ti ọrọ kan lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) pe ki wọn gbe gbogbo ohun to ba n ru wọn ninu ti sẹgbẹ kan ki wọn si ṣiṣẹ papọ fun irẹpọ ẹgbẹ oṣelu wọn.
Makinde fi eyi lede lasiko ti ẹgbẹ oṣelu wọn n ṣe ipade apero ti wọn ṣe agbekalẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ti wọn dibo yan ni ipinlẹ Bauchi.
Gomina Seyi Makinde rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ninu atẹjade to fi sita loju opo Twitter rẹ lati gba gbogbo ọrọ to ba lee fa iyapa laarin wọn danu eyi to n waye gẹgẹ ija laarin ẹgbẹ eyi to ṣẹlẹ lasiko eto idibo to si ni ki wọn si dirọ mọ alafia.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
“A gbudọ gbajumọ awọn nnkan to le mu irẹpọ jọba laarin wa. A tilẹ gbudọ̀ mu u ni ọkunkundun lati doju kọ ohun to n bẹ niwaju a si gbudọ sọ okodoro otitọ fun ara wa. Ohun kan ti mo le sọ ni pe fun awọn gomina PDP to wa nibi, mo le sọ pe wọn ni ẹmi iṣe, wọn ti ṣetan wọn si le ko ipa gidi ninu ẹgbẹ yii”.
Makinde tun fi kun un pe ijọba yoo wa, ijọba yoo lọ ṣugbọn orilẹede yoo ṣi duro.
“Ati pe gẹ́gẹ bi ẹgbẹ oṣelu alatako to wulo, a gbudọ ṣe ohun to tọ ni ifẹ orilẹede wa. Idi eyi ni wipe bi ko ba si Naijiria, ko si awa”.

Oríṣun àwòrán, others
Bi ẹ ko gbagbe, ko farapamọ wipe aarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ko dan mọran rara lasiko eto idibo gbogbo to kọja lọ yii eyi to si jẹ ọpọ maa sọ wipe bi ogiri ko ba la ẹnu, alangba o le wọ ogiri, lo difa fun iwoye ti ọpọ wo wipe gbọnmi sii omi o too inu ẹgbẹ oṣelu PDP lo fa a ti ọpọlọpọ oludije labẹ aburada wọn ṣe lulẹ ni ọpọlọpọ ipinlẹ orilẹede Naijiria ati ni ipele ti ipo aarẹ.










