Wo ìpéjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Èṣù àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ìjọ́sìn, ìgbéyàwó, àtàwọn ayẹyẹ wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ó fẹ́ẹ̀ dàbí wí pé èyí ni àpéjọ àwọn tó ń sin èṣù tó fẹ́ẹ̀ tóbi jùlọ ní àgbáyé, tí yóò sì bẹ̀rẹ̀ ní ilé ìtura Marriott ní Boston láìpẹ́.
Nínú yàrá kan tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti máa fi ṣe ayẹyẹ bí ọjọ èṣù, àmì kan tí wọ́n gbé sí ẹnu ọ̀nà ni yóò kí ènìyàn káàbọ̀ sínú ilé ọ̀hún.
Wọ́n ní orò tí àwọn ń ṣe yìí ni láti fi yí ìrìbọmi tí wọ́n ṣe fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n wà ní kékeré padà.
Wọ́n wọ aṣọ tó gùn gbàgẹ̀rẹ̀, tó ní fìlà lára pẹ̀lú ìbòmú dúdú, wọ́n fi okùn so ọwọ́ wọn èyí tí wọ́n ń tú láti fi ṣàfihàn pé àwọn ti gba òmìnira.
Bákan náà ni wọ́n tún ń ya Bíbélì láti fi ṣàfihàn pé àwọn kìí ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni mọ́.
Ó hàn gbangba pé ètò náà lágbára púpọ̀ fún wọn.

Oríṣun àwòrán, AFP
"Láti ìgbà tí mo ti wà ní kékeré ni àwọn ọ̀rọ̀ bíi pé ní ṣe ló yẹ kí n parun nítorí mo jẹ́ ọkùnrin tó nífẹ̀ẹ́ ìbálòpọ̀ akọsákọ jẹ́ àwọn nǹkan tó máa ń dàmú ọkàn mi, àpéjọ àwọn tó ń tẹ̀lé sàtánì yìí ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrànlọ́wọ́ fún mi."
Ìjọ Sátánì yìí jẹ́ ìjọ tí ìjọba Amẹ́ríkà gbà wọlé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn, tí wọ́n sì ní àwọn olórí àti ọmọ ìjọ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Yúróòpù àti Australia.
Ènìyàn tó lé ní 830 ló gba tíkẹ́ẹ̀tì láti kópa níbi àpérò wọn kan tó wáyé nínú oṣù kẹrin èyí tí wọ́n pè ní SatanCon.
Àwọn ọmọ ìjọ yìí ní àwọn kò ní ìgbàgbọ́ pé Lucifer tàbí pé ọ̀run àpáàdì wà, wọ́n ní àwọn kan ló mọ̀-ọ́n-mọ̀ ń lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí láti fi pa ìròrí àwọn ènìyàn nínú sáyẹ́ǹsì.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Wọ́n máa ń lo àmì èṣù tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ bíi ìgbéyàwó tàbí tí wọ́n bá ń gba orúkọ tuntun. Wọ́n tún máa ń ṣe àfikún wíwọ àgbélèbú lọ́nà òdì, tí wọ́n yóò sì tún máa pariwo "ẹ kírà fún èṣù".
Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ní sísọ ọ̀rọ̀ òdì àti ìbanilórúkọ gbá à ńlá ni èyí.
Agbenusọ Satanic Temple, Dex Desjardins náà gbà pé gbogbo àwọn àwo rán tí àwọn ń lò ló jẹ́ èyí tó lòdì sí Kristẹni.
Ó ní tí àwọn bá ń ṣe ayẹyẹ àwọn máa ń wọ àgbélèbú lọ́nà tí kò yẹ, tí àwọn sì tún máa ń ya Bíbélì láti lòdì sí ìhà tí àwọn ènìyàn kọ sí àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ akọsákọ tàbí abosábo pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sìn kó láyà jẹ ní kékeré èyí tó ní àwọn ló pọ̀ jùlọ nínú àwọn ọmọ ìjọ wọn.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, Others
Àwọn ẹlẹ́sìn èṣù yìí ní àwọn gbàgbọ́ pé gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú àti pé kì í ṣe wí pé àwọn fẹ́ bí àwọn kan nínú pẹ̀lú àwọn nǹkan tí àwọn ń ṣe.
Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ti ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn níwájú ilé ìtura tí àwọn ẹlẹ́sìn Sátánì náà ń lò, tí wọ́n sì ń ṣe ìkìlọ̀ fún wọn.
Ọkan lára àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà láti ìjọ Aguda, Micheal Shiver ní àwọn fẹ́ fi han Ọlọ́run pé àwọn kò faramọ́ ìbanilórúkọjẹ́ yìí àti pé àwọn kò ní òde sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́sìn èṣù.
Onírúurú àkọlé ni àwọn olùfẹ̀hónúhàn ọ̀hún gbé dání tí àwọn ẹlẹ́sìn èṣù sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orí àjà kẹrin ilé ìtura náà ni wọ́n lò fún àpérò wọn.
Onírúurú aṣọ àti ẹ̀ṣọ́ bíi ìwo, èékánná gígùn, àwòrán ara, irunmú tó gùn yàtọ̀ ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn ẹlẹ́sìn náà lò sára.
Wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí Sátánì àti ìtẹ́raẹnilọ́rùn.
Lára àwọn nǹkan tó gbajúmọ̀ tí àwọn ẹlẹ́sìn èṣù yìí máa ń jà fún jẹ́ ọ̀rọ̀ òṣèlú.
Wọ́n gbàgbọ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹ̀sìn àti ìlú, tí wọ́n sì máa ń lọ sílé ẹjọ́ lòpọ̀ ìgbà ní Amẹ́ríkà láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó yẹ kí wọ́n ya ẹ̀sìn sọ́tọ̀ sí ìlú.
Bákan náà ni wọ́n tún ń jà fún pé kí àwọn ènìyàn lè máa ṣẹ́yún bí ó ṣe wù wọ́n.
Wọ́n ní ó yẹ kí àwọn ènìyàn lè máa ṣe ohun tó wù wọ́n pẹ̀lú ara wọn.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, wọ́n dá ilé ìwòsàn orí ayélujára kan kalẹ̀ ní New Mexico èyí tí àwọn ènìyàn tì lè máa ra oògùn oyún ṣíṣẹ́ lórí ayélujára.
Àwọn ìgbésẹ̀ yìí ti ń fa kí àwọn kan bíi ìwé ìròyìn ìjọ Aguda, National Catholic Register máa bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ètò yii.
Ètò àwọn ẹlẹ́sìn èṣù yìí tó tún ń fa awuyewuye báyìí ni ètò kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ èyí tí wọ́n pe àkọmọ̀nà rẹ̀ ní "ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú èṣù".
Wọ́n ṣetán láti máa kọ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀sìn lẹ́yìn àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ní àwọn kò nífẹ̀ẹ́ sí kí àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn náà máa kọ àwọn ọmọ ní ìyìnrere ní ilé ẹ̀kọ́.
Ohun tí ẹ̀kọ́ ẹgbẹ́ ọ̀hún dá lé lórí ni ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìrònújinlẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Èṣù fẹ́ràn rẹ

Oríṣun àwòrán, Others
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ìtajà ló ti ń gbé àwọn ọjà tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwòrán èṣù sórí igbá.
Àwọn ìṣeré ọmọdé tí wọ́n kọ èṣù fẹ́ràn rẹ sí, orí ewúrẹ́ tó ní ìyẹ́, aṣọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n ń tà.
Ènìyàn kò nílò láti san owó kankan láti darapọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́sìn èṣù, ìtọrẹ àánú tí wọ́n ń rí gbà ni wọ́n ń lò láti fi ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe.
Ìwé kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọdé ló ti ń mú kí àwọn ènìyàn máa kọ hà!
Òpó méje ni àwọn ẹlẹ́sìn èṣù gbé ẹ̀sìn wọn lórí èyí tó fi mọ́ bíbọ̀wọ̀ fún ọmọlàkejì, ṣíṣe ohun tó bá wu ni pẹ̀lú ara ẹni, fífi ààyè gba ẹlòmíràn láti ṣe ohun tó bá wù wọ́n àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Araceli Rojas tí òun náà báwọn kópa níbi ayẹyẹ náà ní ọdún 2020 ni òun kọ́kọ́ mọ̀ nípa ẹ̀sìn yìí.
Ó ní ẹ̀rù kọ́kọ́ bá òun ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ pé ṣé kìí ṣe wí pé wọ́n ń fi ọmọ rúbọ àmọ́ nígbà tí òun mọ̀ nípa wọn dáadáa ni òun ri dájúdájú pé ènìyàn dáadáa ni wọ́n.

Oríṣun àwòrán, Others
Ọ̀pọ̀ àwọn tó bá BBC sọ̀rọ̀ ní àbọ̀ ìwádìí Hail Satan tí wọ́n gbé jáde lọ́dún 2019 ló jẹ́ kí àwọn mọ̀ nípa ẹ̀sìn yìí.
Ìjọ Satanic Temple ní àwọn ọmọ ìjọ àwọn ti tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin báyìí láti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́dún 2019.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ yìí ní àwọn kìí lè sọ pé àwọn wà nínú ìjọ náà níta nítorí ọ̀pọ̀ ló ti pàdánù iṣẹ́, tí wọ́n sì ń dún okò mọ́ àwọn mìíràn.
Chalice Blythe tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn agbenusọ TST ní láti ọdún 2016 ni àwọn kan ti ń lépa ẹ̀mí òun lẹ́yìn tí ẹbí òun kan fi orúkọ òun léde.
Ó ní agbébọn ti wá ṣe ìkọlù sí òun nílé rí láti pa òun nítorí ẹ̀sìn tí òun yàn láàyò.















