Iṣẹ́ àwọn ọ̀tá ni ìròyìn tó ní mo má n lu ìyàwó mi - Igbákejì gómìnà Ondo

Oríṣun àwòrán, Others
Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Lucky Aiyedatiwa, ti sọ pe ayederu ni iroyin to n lọ pe oun ma n lu iyawo oun.
Iroyin sọ pe àjọ kan to n ro awọn obinrin l'agbara lo fi ẹ̀sùn kan Ọgbẹni Aiyedatiwa pe o ma n lu iyawo rẹ, Arabinrin Oluwaseun Aiyedatiwa.
Àjọ naa gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ní igbakeji gomina ti lu iyawo rẹ ni ìgbà meji laarin oṣu mẹrin, eyi "to tako ilana ipo rẹ gẹgẹ bi igbakeji gomina".
Ṣùgbọ́n ninu atẹjade kan to fi sita lati ọwọ́ agbẹnusọ rẹ, Kenneth Odusola, Ọgbẹni Lucky Aiyedatiwa sọ pe oun ko gbe ọwọ́ soke lu iyawo oun rí lati igba ti wọn ti ṣe igbeyawo.
Ọgbẹni Odusola sọ pe iyawo igbakeji gomina ko si ni Naijiria lọwọlọwọ.
"Kii ṣe nǹkan àṣírí pe orile-ede United Kingdom ni Arabinrin Oluwaseun Aiyedatiwa n gbe, to si ti n ṣiṣẹ́ lati ọjọ́ pipẹ, koda ki ọkọ rẹ to o de ipo oṣelu.
"Nitori naa, isẹ ọwọ́ awọn ọta ipinlẹ Ondo, to fẹ da wahala silẹ ni iroyin tó bá ní ìwà ipá n sẹlẹ ninu idile igbakeji gomina."
Agbẹnusọ fun Ọgbẹni Aiyedatiwa tun salaye pe iṣẹ ti Gomina Rotimi Akeredolu gbe le igbakeji rẹ lọwọ, ni onitọhun mojuto lati bi oṣu mẹrin ti iroyin sọ pe o ti n lu iyawo rẹ. O ni iroyin yii ko jẹ́ àjèjì sí àwọn rara, nitori pe àṣírí ti tu ni ọpọlọpọ ọ̀sẹ̀ ṣẹyin, nipa bi awọn eeyan kan ṣe fẹ da wahala silẹ nipinlẹ Ondo. Ọgbẹni Aiyedatiwa ni ijiya to tọ n duro de àwọn to n gbe iru iroyin bẹẹ jade, tí wọn ko bá jawọ.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post












