Iyabo Ojo: Àwọn akọ̀ròyìn ń pè mí ní aṣẹ́wó tori n kò sí nílé ọkọ

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja oṣerebinrin to tun jẹ ilumọọka apanilẹrin lori ayelujara, Iyabo Ojo, ti sọrọ lori bi igbeyawo rẹ ṣe tuka.

Bakan naa lo mẹnuba iya to ni oun jẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria tori pe oun sọrọ soke.

Lasiko ayẹyẹ ọdun Ajinde ni Iyabo Ojo n fi eyi dupẹ lọwọ Ọlọrun gẹgẹ bo ṣe gbe aworan oun atawọn ọmọ rẹ mejeji saya.

Nibẹ lo si ti n kọ orin "Oṣuba rẹ ma re o" tọkan tọkan ninu fidio kan.

Labẹ fidio naa lo ti kẹnu bọ ọrọ to si ni "Ta a ni mi gan ti mi oni mọ oore rẹ, mi o ni dakẹ lati maa mọ riri rẹ Ọlọrun".

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Lẹyin idupẹ ni Iyabo Ojo ba kẹnu bọ ọrọ iriri oun to ni aye sọ ọ da ati paapaa awọn alakalẹ bo ṣe ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria yi kadara oun da tan, Ọlọhun ni ko gba.

Eni, eji, ẹta, titi dori aarun lo fi kọ ọrọ rẹ sabẹ onka eyi ti BBC Yoruba ṣe atupalẹ rẹ.

Awọn ọna ti Iyabo Ojo ni ọmọ Naijiria gba fiya jẹ oun:

Lakọkọ, iyabo Ojo ni awọn ọmọ Naijiria ṣe idẹyẹsi oun nitori pe oun kọ ọkọ silẹ.

Gẹgẹ bii oun to sọ, n ṣe lawọn eeyan maa n bu ẹnu atẹ lu oun laarin ilu nitori igbesẹ naa ti oun gbe.

O ni "Gẹgẹ bii abiyamọ ti ko si nile ọkọ, n ṣe lo da bi pe ilẹ okeere ni mo n gbe lai ni iwe igbelu lọwọ."

Lẹyin naa lo ni awọn akọroyin fun oun ni orukọ 'Aṣẹwo' to jẹ eyii to buru julọ ninu gbogbo ohun ti wọn ṣe fun oun.

Iyabo Ojo tun sọrọ lori bo ṣe jẹ oṣere tiata ati idojukọ to ba pade nibẹ

O ni "Iṣẹ tiata ti mo yan laayo fun awọn eeyan kan ni ẹri aridaju pe isẹ aṣẹwo gan ni mo n ṣe.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Gbajumọ oṣere naa tun mẹnuba idojukọ to ba pade nitori pe ẹka iṣẹ tiata ede Yoruba lo ya si.

Wọn ni ara oko ni mi ti mo ba sọ Gẹẹsi:

Nitẹsiwaju ọrọ rẹ, Iyabo ni awọn kan pe oun ni ara oko ti oju rẹ ko ri ita, paapaa to ba sọ ede Gẹẹsi.

O ṣalaye pe ni ṣe lo maa n ya awọn mii lẹnu pe oun tilẹ le sọ ede Gẹẹsi to dan mọran lẹnu.

Lakotan, Iyabo ni awọn eeyan pe oun ni alainitiju lẹyin ti oun sọrọ soke nipa awọn iriri ile aye oun.

Lẹyin naa lo gba awọn ololufẹ rẹ niyanju lati dẹkun igbe aye to kun fun iwa eke tabi ayederu.

O ni "Jijẹ olootọ si ara mi ati okun inu ti mo ni, lo gbe mi de ipo ti mo wa loni yii."

"Mo maa tẹsiwaju lati maa sọrọ soke nipa iriri aye mi lati ṣe iwuri fun awọn obi bii temi bayii.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó