Nigerian Spider Man Jonathan Olakunle: Naijiria nílò ènìyàn tó fẹ́ràn ìmọ́tótó bii tèmi

Spiderman ni Osogbo

Olakunle to jẹ onimọ nipa imọtoto ayika lo wọ aṣọ Spider man lati tun agbegbe rẹ ṣẹ.

Arakunrin ọmọ Naijiria, Jonathan Olakunle to n wọ aṣọ bii ''Spider Man'' ninu fiimu ti ileeṣẹ Marvel gbe jade, ti sọ idi ti oun fi n ṣe bẹẹ lasiko to ba n gbalẹ ni igboro ilu Osogbo.

Olakunle, lasiko to n ba BBC sọrọ ni awọn eniyan ko kọ ibi ara si imọtoto ni ayika lo jẹ ki oun dide lati maa ṣe imọtoto.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olakunle to jẹ onimọ nipa imọtoto ayika lo wọ aṣọ Spider man lati tun agbegbe rẹ ṣe.

Gẹgẹ bi ọrọ Banki Agbaye, awọn idọti ti wọn kojọ ni awọn ilu nla nla le ni biliọnu meji tọọnu.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Ki lo sun Olakunle de idi fifi asọ SpiderMan gba ilẹ igboro:

Ninu ọrọ rẹ, Olakunle ni oun ko fẹran bi oun ṣe ma n ri idọti ni ayika oun, oun si korira ayika ti o doti.

'Ọjọ kan ni mo bẹrẹ si ni gba adugbo lẹyin ti mo kuro ni ile, mo bẹrẹ ninu ile, ki agbegbe mi le mọ toto''

Idi ti mo fi n wọ aṣọ Spiderman ni lati jẹ ki awọn eniyan kọ bi ara si mi nitori nigba ti mi o wọ aṣọ Spiderman, awọn eniyan ko tilẹ da mi loun, ti mo ba n gbalẹ.

Igbakigba ti mo ba pe wọn, wọn ko ni dahun amọ nigba ti mo wọ aṣọ alaranbara yii ni wọn ma n dami lohun, ti wọn a si tun darapọ mọ mi.''

O ya mi lẹnu pe ti awọn ọmọ Naijiria ba rinrinajo lọ si oke okun, wọn ma n tẹle ofin ati ilana lori imọtoto amọ ni Naijiria, wọn kii kọbi ara si''

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

Ẹ jẹ ka mu imọtoto ni pataki lati sẹgun aisan - Olakunle

Imọtoto lo bori arun gbogbo paapaa awọn aisan to wọpọ ni ilẹ adunlawọ bii aisan onigbameji, aisan iba apọnju, aisan iba Lassa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Nitori naa ni Olakunle ṣe rọ gbogbo awọn ọmọ Naijiria, to fi mọ awọn ọdọ lati mu imọtoto ni ọkunkundun fun igbayegbadun awọn eniyan.

Iwadii fihan pe, ọpọlọpọ idọti ti o wa ni awọn ilu nlanla ni wọn n parapọ si awọn agbegbe, eleyii ti yoo mu aisan wọpọ ni awọn agbegbe yii.