Itunu Lawal allegedly killed by husband: Láàrin ọdún méjì ìgbéyàwó, ọmọ mi àti ọkọ rẹ bẹ̀rẹ̀ ìjà tó gbóná

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Bi ẹ ko ba gbagbe, iroyin tan ka ni ọjọ melo kan sẹyin nipa arabinrin kan ti wọn ni ọkọ rẹ pa, iya iyawo ree to n ba BBC Yoruba sọ ọrọ bo ṣe jẹ.

Arabinrin Esther Asuquo to jẹ iya to bi Itunu Lawal ṣalaye pe ọtọ ni nkan ti awọn idile baba ọmọ oun sọ lori foonu pe o ṣe Itunu ki oun maa bọ nileewosan amọ "bi mo ṣe de ibẹ, oku ọmọ mi ati oku ọmọ rẹ to ṣẹ bi, oku eeyan meji ni mo ba lẹyin mọto ti wọn gbe wọn si o".

Igbeyawo Itunu ati Ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bawo lo ṣe bẹrẹ?

Itunu Lawal ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iya Itunu ṣalaye bi igbeyawo Itunu ati ọkọ rẹ ṣe waye ti wọn fẹ ara wọn niṣu lọka ni ọdun 2018 ti Ọlọrun si fun wọn ni ọmọbinrin.

"Gbogbo nkan n lọ ni mẹlẹmẹlọ lai si wahala ko to di ọdun 2019". Iya yii ni wọn pe oun nigba ti ija bẹrẹ laarin wọn toun si ba wọn pari rẹ niwọnba bi oun ṣe jẹ iya iyawo.

Iyalẹnu lo jẹ fun iya to ni oun ri apa lara ọmọ rẹ nigba to wa ki i ninu oṣu kejila.

"Mo pe ọkọ rẹ lori foonu, mo fi ọrọ ranṣẹ sii, a ni oun n lọ ibiṣẹ ni gbogbo igba".

Iya Itunu ni gbogbo igba ni ko raye wa ri oun titi ti ọmọ oun fi pe oun pe ọkọ oun ko wale mọ o, o ni ki oun lọ bẹ iya oun koun to le wa sile, o si ni ọmọ oun tun ṣe bẹẹ nilẹ Enugu.

Itunu Lawal ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iya ni ifẹ yii naa ni ọmọ oun fi n kẹwọ titi titi ti ọkọ naa si kọ ti ko lọ ri iya Itunu.

Iroyin ti yoo tẹle e ni ipe to gba lorii foonu pe wọn ni ọmọ oun Itunu bimọ o si daku amọ ọtọ lohun to ba nibẹ tori ati ọmọ rẹ ati ọmọ ti o bi, oku awọn mejeji ni o ba.

Iya n fẹ idajọ, ẹbi baba Itunu fi Ọlọpaa gbe ọkọ, wọn tun ti tu u silẹ

Iya Itunu Lawal

Arabinrin Esther sọ fun BBC Yoruba pe bi oun ṣe fẹ bẹrẹ ẹjọ pẹlu ọkọ ọmọ oun ni ilana ofin ni wọn sọ fun oun pe o wa ni "coma".

"Nigba ti mo tun maa fi bẹrẹ pada mo gbọ pe awọn ile baba Itunu ti fi Ọlọpaa gbe e amọ bi a ṣe n sọrọ̀ lọwọ yii, wọn ti tu u silẹ".

Ẹwẹ, BBC Yoruba kan si Ọlọpaa lati mọ oun to ṣẹlẹ gangan.