Domestic Violence: Afurasí apààyàn ṣàlàyé ìdí tó fi fọ́ orí ọmọ rẹ̀ oṣù kan mọ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, Lagos state police
Arakunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan Benedict Anieze ti ko si panpẹ ọlọpaa lori ẹsun pe o fọ ori ọmọ rẹ mọlẹ.
Ladugbo Idimu ni ilu Eko la gbọ pe o ti pa ọmọ osu kan rẹ yii .
Gẹgẹ bi ileesẹ ọlọpa ti salaye, ija to waye laarin arakunrin naa ati iyawo rẹ lo mu hu iwa yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí lò fa ariwo pe Wasiu Ayinde kó kúrò nílé fún Ropo, aya rẹ̀ torí pé obìnrin náà fọ léti torí obinrin miran?
- Ènìyàn 150 farapa bí ìkọlù tuntun ṣe bẹ̀rẹ̀ ní mọ́ṣáláṣí al-Aqsa
- Ooni Ilé Ife, Adeyeye Ogunwusi ti bí ọmọ míràn?
- Àwọn ọlọ́pàá ti mú ọmọbìnrin tó parọ́ pé wọn jí òun gbé, fi ipá ba òun lòpọ̀
- Ọ̀dọ́ afurasí adigunjalè méjì, Oyewusi àti Anini tú àṣírí bí ìyá wọn ṣe jẹ́ agbodegba wọn
- Òṣìṣẹ́ INEC kàn ku méjì, dì àwáti bí agbébọn ṣe kọlù ibùdó iforukọsilẹ
- Seyi Makinde ti sọ Auxillary di nǹkan míì sígbòrò, ọlọ́pàá gbọdọ̀ mu - Olopoeyan
- Wo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí o lé rì sínú ọwọ́ rẹ̀ láti má a san owó ọ̀jà láì lo káàdì ATM
Amọ ọgbẹni Benedict ti sọ pe oun ko mọọmọ pa ọmọ naa.
Afurasi naa mọọmọ pa ọmọ rẹ osu kan ni nigba to mu ọti yo - Ileesẹ ọlọpaa
Ewẹ, ileesẹ ọlọpaa ti tako ọrọ rẹ yi iti wọn si ti fẹsun kan pe o seku pa ọmọ naa lasiko to mu ọti yo ni.
Alukoro ọlọpaa Eko, Hundeyin lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni:
''Ọrọ yii nise pẹlu isekupa ọmọ osu kan, Onyiyechi Anieze, lati ọwọ baba rẹ Benedict Anieze ni adugbo Idimu ni Eko.
Ọjọ Kẹfa osu Kẹrin ọdun 2022' si ni isẹlẹ naa waye."
O tẹsiwaju pe ''Benedict lo seku pa ọmọ́ naa lasiko to mu ọti yo, to si fọ ori ọmọ naa mọlẹ lẹyin toun ati iyawo rẹ tahun si ara wọn.
Laipẹ yii ni a o gbe afurasi yi lọ si ileẹjọ''
"Ọmọ mi yọ jabọ lọwọ mi, lo fi ori gbalẹ"
Afurasi naa, nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ gba pe, lootọ loun pa ọmọ naa sugbọn o ni oun ko mọọmọ ati pe ọmọ naa yọ jabọ lọwọ oun ni.
O salaye pe ''baluwẹ ni mo wa nigba ti mo gbọ ti eeyan kan n kan ilẹkun.
Mo sare jade lati gbe ọmọ mi sugbọn o yọ jabọ lọwọ mi to si fori gbalẹ''
'' Kete ti mo ri nkan to sẹlẹ, mo sa jade kuro ninu ile, ti mo si lọ gbe galọọnu epo bẹntiroo, ti mo si fẹ dana sun ara mi nitori nkan to sẹlẹ.
Mi o mọmọ seku pa ọmọ yii. Mi o ki n se ẹni to n fi ọmọ rubọ''
O fi kun pe oun ko fọ ori ọmọ naa mọlẹ gẹgẹ bi awọn ọlọpaa se sọ.
''Nigba ti isẹlẹ yi waye, mi o rojutu ara mi mọ. Nise ni mo fẹ da bẹntiroo si ara ki n si dana sun ara mi.
Mi o dunnu si oku ọmọ mi to wa nilẹ. Nkan to wa si mi lọkan ni ki n pa ara mi.
Emi ati iyawo mi ko ni ede aiyede kankan saaju ọjọ taa n wi yi.

''Àti ọmọ ọdún mẹ́fà ni mo tí ń fa Cocaine, bí mo ṣe fipá bá Tosin lòpọ̀ rè é, tí mo sì pa á''

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti ni wọn gbe afurasi Ikenna naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n risi ọrọ iwa ipa lawujọ(CID) fun iwadi ẹkunrẹrẹ.
Arakunrin ẹni ọdun metalelogun, Ikenna James Joshua ti wọn funra si pe o gbẹmi ara ile rẹ ti salaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
Joshua to ni kii ṣe oun nikan lo ṣọṣẹ yii, jẹwọ bi awọn ṣe pa arabinrin Adefisayo Tosin to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ti wọn jọ n gbe ile kan naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo fẹ́ pokùnso torí ìjákulẹ̀ tí ọ̀gá mi, Yekini Ajileye fún mi, ọpẹ́ tọ́ọ́gì kan... - Abija
- IPOB àti Yoruba Nation ń gbèrò ìwọ́de alágbára
- Nǹkan márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Peter, ọkọ Osinachi, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ikú aya rẹ̀ kàn
- Ọdún mẹ́jọ ni ọkọ ọmọ mi kò jẹ́ ki n fojú kan ọmọ mi lẹ́yìn ìgbéyàwó - Ìyá Osinachi
- Ẹ̀yin obìnrin, ẹ tètè jápa tí ìgbéyàwó yín bá ti la ìgbájú-ìgbámú lọ - Olori Silekunola
- Ẹ dákun, ẹ gbà mí, Auxillary ń lépa ẹ̀mí mi - Olopoeyan kọ̀wé sí ọlọ́pàá, DSS
- Buhari, 2023 pẹ́ jù, àsìkò tó láti kọwe fí ipò sílẹ̀ - Àgbààgbà Àríwá
- Kí ló dé tí ẹnu ń kun ìgbeyàwó Funke Akindele pé ó ti dàrú? Àbọ̀ ìwádìí wa rèé
- Ó ti tán fún Nàìjíríà bí ará Àríwá bá tún di Ààrẹ lọ́dún 2023 - Adebanjo
- Ọdún mẹ́jọ ni ọkọ ọmọ mi kò jẹ́ ki n fojú kan ọmọ mi lẹ́yìn ìgbéyàwó - Ìyá Osinachi
- Àkàrà tú sépo fún ayédèrú ọ̀gágun tó fi Khaki lú jìbìtì N266.5m
Iṣẹlẹ naa to waye ni oru ọganjọ, ṣẹlẹ ni agbegbe ilu Ogijo, nipinlẹ Ogun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abinbola Oyeyemi ni lọọto ni wọn pa arabinrin Tosin to ṣetan lati fasiti Obafẹmi Awolowo, lẹyin ti wọn wọ yara rẹ lati ja a lole, ti wọn si pa a.
Oyeyemi ni Ikenna jẹwọ pe lootọ ni oun ati ekeji oun pa Tosin ti awọn lọ ja lole, nitori o da awọn mọ.
Iya Ikenna to sọ pe inu oun dun si bi awọn ọlọpaa ṣe ri ọmọ naa mu ni ọmọ buruku ni lati ilẹ.
Ikenna nigba to n sọ itan rẹ ni ipinlẹ Imo ni awọn ti wa, amọ Ogijo ni ipinlẹ Ogun ni awọn n gbe. Ti oun si wa si ilu naa ni ọdun 2017.
''Baba mi ti ku', ọdọ iya mi ni mo n gbe pẹlu rẹ.''
''Ni Ọjọ Kẹta, Oṣu Kẹrin ni mo ji ẹrọ iranṣọ ti iyawo ẹgbọn mi gbe si ọdọ iya mi, ti mo si ta a ni ẹgbẹrun mẹrin naira.''
''Nigba ti iya mi de lati ile ijọsin ti ko ri ẹrọ iranṣọ ni mo sa kuro ni ile ti wọn si bẹrẹ si ni pe mi.''
''Mo sa lọ si ọdọ ọrẹ mi Rasheed ti mo ta ẹrọ iranṣọ naa fun, oun lo si gba mi ni iyanju ki n wa iṣẹ ṣe nipa jija awọn eniyan ni ole ohun ini wọn.''
''Ni alẹ ọjọ naa lo ni ki n wa ọna bi mo ṣe ma a ri ẹrọ iranṣọ to pọ si. Bẹẹ si ni mo mọ arabinrin kan to n jẹ Tosin ti a jọ n gbe inu ile kan naa pẹlu iya mi, yara rẹ lo tẹlẹ ti wa, nitori naa mo sọ fun Rasheed pe Tosin ni ẹrọ iranṣọ meji, o si ni ka jawọ ile rẹ ni oru, ki a so mọlẹ ki a si ji awọn ohun ini rẹ.
''Ni aago kan oru ni a wọ ile rẹ, ti ẹru si baa lati ri wa, nigba naa ni Rasheed ni ki n de ọwọ rẹ mọlẹ ati ọna ọfun rẹ, ti o si bẹrẹ si ni ba ni ajọṣepọ.''
''Lẹyin to pari ni emi naa ba gun le, bi o ṣe bẹrẹ si ni pariwo niyẹn lẹyin to ri oju wa, eleyii to mu mi de ọna ọfun rẹ mọlẹ si ti mo si fi aṣọ bo oju rẹ. Eyi jẹ ki o rẹ ẹ ti ko si le mi daadaa.
''Lẹyin naa ni a ji ọkan lara ẹrọ iranṣọ rẹ, irẹsi, ẹwa, spaghetti, waya ati foonu rẹ, amọ a ko ri owo kankan.''
''A bẹrẹ si ni wa owo kiri amọ a ko ri lo jẹ ki a pẹ ki a to gbọ ti iya Tosin wa kan ilẹkun rẹ, ti wọn si ri iho ti a gba lati wọ inu ile rẹ, bakan naa ni awọn vigilante wa ni tosi.''
''Mo mọ pe o ti bọ fun mi, ti a si tiraka lati salọ, amọ bi mo ṣe n bẹ silẹ lati ori orule ni mo bọ si ọwọ awọn vigilante, sugbọn Rasheed ti salọ ni tirẹ.''
''Lẹyin ti wọn bẹrẹ si ni na mi ni mo jẹwọ pe Tosin ti ku si inu ile ati bi a ṣe pa a.''
Bi mo ṣe bẹrẹ igbesi aye mi ni yii…
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, Ikenna ni ọdun meji ni oun wa ti baba awọn ti ku, ti iya awọn ko si si pẹlu wọn ni igba naa.
Ikenna ni awọn ẹbi ti wọn ko wọn ti fi wọn silẹ ti wọn si le oun ati ẹgbọn oun obinrin kuro ni inu ile nitori wọn ko le e tọju wọn mọ.
''Wọn mu ẹgbọn mi agba lọ si ọdọ ẹnikan ni ilu Abuja lati lọ ma a gbe nibẹ, ti emi si n rin arinka.''
''Lati kekere bi ọmọ ọdun mẹfa ni mo ti bẹrẹ si ni mu oogun oloro Cannabis ni Idi Oro, ni agbegbe Mushin, ni ipinlẹ Eko.''
''Mo ṣetan ni ile ẹkọ girama amọ mi o le ko idanwo WASCE nitori aisi owo ati oluranlọwọ.''
''Yatọ si Cannabis, mo tun n mu Cocaine, Colorado, amphetamine ti wọn n pe ni Ice to fi mọ Loud ati Sckuchies to jẹ adapọ oogun oloro codeine,zobo ati omi.''
Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti ni wọn gbe afurasi Ikenna naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n risi ọrọ iwa ipa lawujọ(CID) fun iwadi ẹkunrẹrẹ.
Bakan naa lo paṣẹ ki wọn wa Rasheed ni awari, ki awọn mejeeji si foju wina ofin.






















