2023 General Elections: Adebanjo ni afọ́jú ni adarí àti àwọn èèyàn Nàíjíríà tó jẹ́

Alagba Ayo Adebanjo

Oríṣun àwòrán, Ayo Adebanjo

Adarí ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá, Alagba Ayo Adebanjo ti n kọminú lórí bí ohun gbogbo kò ṣe rọgbọ ní Nàìjíríà.

Adebanjo ní ó ṣe ni láàánú wí pé afọ́jú ni àwọn adarí àti àwọn ènìyàn Nàìjíríà, tó jẹ́ wí pé wọn kò mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ.

Adarí Afenifere náà fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn ninu ifọrọwerọ kan to se lati sami ọjọ ibi ọdún Kẹrìnléláàdọ́rùn-ún rẹ lókè eèpẹ̀.

Ó ní gbogbo ìgbà ni omi inú máa ń kan òun, tí ọkàn òun sì máa ń bàjẹ́ tí òun bá rántí irú ipò tí Nàìjíríà wà báyìí.

Àmọ́ ó fi kun wí pé tí Ààrẹ Muhammadu Buhari bá le gba gbogbo ìpè èyí tí àwọn ti ń pè fún láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn láti wá àtúnṣe sí ìwé òfin Nàìjíríà tàbí dá orílẹ̀ èdè padà sí lílo ìwé òfin tí à ń lò tẹ́lẹ̀, yóò ṣe àǹfàní púpọ̀ fún Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

Bàbá Adebanjo tẹ̀síwájú wí pé ìwé òfin tí Nàìjíríà ń lò báyìí jẹ́ èyí tí àwọn ológun ṣe kalẹ̀, léyìí tó ń ṣègbè fún ẹ̀yà kan, fún ìdí èyí kò le so èso rere fún ìjọba alágbádá.

Kò sí ohun tó le mú àyípadà bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àyàfi...

Pa Adebanjo ní gbogbo ìgbà ni òun máa ń sọ ọ́ wí pé àyàfi tí orílẹ̀ èdè yìí bá pa ìwé òfin tí à ń lo lọ́wọ́ yìí tì kí a ṣe àgbékalẹ̀ ìwé òfin mìíràn, ojú kan náà ni Nàìjíríà yóò ti máa fò tí yóò sì máa bà síbẹ̀ bákan náà.

Ó ní ní kété tí àyípadà bá ti bá ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí, ìgbà ọ̀tun yóò dé fún mùtúmàwà, tí inú àwọn ènìyàn yóò sì máa dùn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pàbó ni gbogbo ìgbìyànjú yóò máa jásí.

Nígbà tó ń fèsì lórí ètò ìdìbò ọdún 2023, Adebanjo ní asán báńsá ni ètò ìdìbò náà yóò jẹ́ bí ìjọba bá kọ̀ láti mú àtúntò bá Nàìjíríà kó tó di ìgbà náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀rọ̀ El-Rufai ti fi hàn wí pé nǹkan ńṣe ètò ààbò Nàìjíríà

Bàbá tún tẹ̀síwájú wí pé ìjọba ti kùnà lórí dídá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn léyìí tó ní ó ṣe kókó sí ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè tó bá fẹ́ gòkè.

Ó ní ó ṣeni láàánú wí pé lẹ́yìn ìkọlù àwọn agbébọn sí ọkọ rélùwéè, El-Rufai ní àwọn gómìnà ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Àríwá ti ń dúnkokò láti wá àwọn ológun láti ilẹ̀ òkèrè bí ìjọba bá kọ̀ láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ètò ààbò tó ti dojúrú.

Adebanjo tun kọminú pé láti ìgbà tí gómìnà ìpínlẹ̀ Borno àti ti Niger ti ń ké tantan wí pé àwọn Boko Haram ti gba àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mélòó kan ní ìpínlẹ̀ àwọn, kò sí ohun kankan tí ìjọba rí ṣe sí ọ̀rọ̀ náà.

Bákan náà ló tún wòye wí pé láti ìgbà tí ọ̀gágun kan ti ní òun ti fi orúkọ àwọn tó ń ṣàtìlẹyìn fún ikọ̀ Boko Haram ráńṣẹ́ sí Ààrẹ, kò sí ohun tó ti tẹ̀yìn rẹ̀ yọ.

"Láti bí oṣù mẹ́fà sí àsìkò yìí, kò sí ọjọ́ kan tí kò sí ìròyìn nípa ìsẹkúpani, ìjínigbé tàbí ìfipábánilopọ̀ ní orílẹ̀ èdè yìí."

"Ìjọba lábẹ́ ìdarí Buhari ti kùnà ní gbogbo ẹ̀ka ṣùgbọ́n àwọn kan ṣì ń tan ara wọn, ètò ẹ̀kọ́ kò lọ bó ṣe yẹ, gbogbo àwọn ọ̀dọ́ ń sá lọ sí ilẹ̀ òkèrè láti wá ìgbé ayé tó rọrùn."

"Kí ló dé tí Ààrẹ Buhari kò le bá Nnamdi Kanu àti Sunday Igboho jíròrò láti mọ̀ ìdí tí wọ́n ṣe fẹ́ kúrò lára Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe pẹ̀lú àwọn Boko Haram."

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

Ìdìtẹ̀gbàjọba ń rùn lórí Nàìjíríà

Bàbá Adebanjo ni pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe ń ló ní Nàìjíríà báyìí kò sí bí ìdìtẹ̀gbàjọba kò ní wáyé ní orílẹ̀ èdè yìí àti pé ìjàgbara kìí ṣe ọ̀fẹ́, wọ́n máa ń jagun gbàá ni.

Pẹ̀lú bí àwọn ènìyàn bíi Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu ṣe ti ń dìde láti jà fún ẹ̀tọ̀ wọn, kò sí ìgbà tí àwọn mìíràn bíi ti wọn náà kò ní dìde, àwọn ènìyàn ma tó fọ́n sí títì láti jà fúnra wọn.

"Ìran tó ń bọ̀ ni àyà mi ń já fún lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà nítorí bí èmi ṣe wà, sàárè ni mò ń wò báyìí, àbí máa sọ wí pé Ọlọ̀run kò sẹ oore fún mi lẹ́ni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́rùn-ún lókè eèpẹ̀."

"Èmi mọ̀ pé kò sí ohun kan tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ètò ìdìbò ọdún tó ń bọ̀, tí Nàìjíríà bá ṣì dúró gẹ́gẹ́ bí ẹyọ kan, a kú oríire."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀