Afenifere sọ̀rọ̀ àbùkù sí agbẹnusọ Buhari lẹ́yìn tó tako àwọn tó ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ournaijanews
Ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afenifere ti sọko si agbẹnusọ Aarẹ Muhammadu Buhari, Femi Adesina, lori bo ṣe tako awọn to n bu ẹnu atẹ lu ijọba to wa lode.
Akọwe agba ẹgbẹ Afenifere, Sola Ebiseni lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan pe ijọba Buhari ti ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ, o si tọ ki awọn araalu maa sọrọ abuku si.
Ṣaaju ni Adesina ti kọkọ sọ pe oun dẹkun lati maa lọ si ṣọọṣi kan niluu Abuja nitori pe alufaa ijọ maa maa n bu ẹnu atẹ lu iṣẹjọba Buhari.
- Alùlùgbayì ọmọ Nàìjíríà tó fI Ìlù kojú ìdẹ́yẹsí ní Amẹ́ríkà rèé
- Taaooma tọrọ aforíjìn lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ pé ó bá ìgbákejì ààrẹ ṣèpàdé, èsì Mr Macaroni àtàwọn ọdọ́ rèé
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- Màá ṣèrànwọ́ láti dojú ìjà kọ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ nílẹ̀ Niger tó pa èèyàn 69 - Buhari
- Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá sọnù sínú ìjàmbá iná Kẹrosínìì l‘Abuja
- Èèyàn 94 kú lásìkò tí wọ́n ń gbọ́n epo bẹntiróòlù
- Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ oo! Ìyá ju ọmọ rẹ̀ méjì sí Kànga
- Ìdìbò gómìnà Anambra gbérasọ, ìíú dá wáí-wáí, aráàlú ń sá kíjo kíjo
- "Ó dùn mí pé èmi ló bí Abubakar Shekau tó dá ayé lóró"
Atẹjade ọhun ni lati igba aye awọn wolii ninu bibeli ni wọn ti maa sọrọ si ijọba ti asiko ba n ni awọn araalu lara.
O ni "Laye igba ti wa yi gan, awọn ojiṣẹ Ọlọrun bii Martin Luther king, Desmond Tutu, Biṣọọbu agba Okogie, Biṣọọbu Gbonigi, Matthew Kukah, Tunde Bakare atawọn mi ko dẹkun lati maa ba ijọba sọ ootọ ọrọ ti wọn ko ba ṣe daadaa."
Afenifere sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ojiṣe Ọlọrun kan n ba ijọba sọ ootọ ọrọ, awọn ojiṣẹ Ọlọrun mii wa ti wọn ko le ba ijọba ijọba sọ eyii tii ṣe ododo ọrọ nitori ohun ti wọn yoo jẹ.
Ẹgbẹ ọmọ Yoruba naa tẹsiwaju pe irufẹ awọn ojiṣẹ Ọlọrun bẹẹ lo n tan Aarẹ Muhammadu Buhari jẹ pe o le maa ṣe ohun to wu bii ko maa fi iya jẹ awọn ajijabara nigba ti awọn ọdaran n yan fanda laarin ilu.
O ni "A ni awọn iranṣẹ Ọlọrun kan bii awọn irinwo wolii Ahabu ninu bibeli ti wọn n doju ija kọ Michaili, awọn lo n jẹ ki awọn adari tubọ maa ṣe aṣiṣe si."
"Irufẹ awọn olubadamọran bẹẹ pọ ninu ijọba yii ti wọn jẹ ki Aarẹ gbagbọ pe o lagbara lori ilẹ awọn ẹya kan, ati pe wọn le yan lati fọwọ mu ilẹ wọn tabi ẹmi wọn."
"Awọn eeana yii kan naa ni wọn n tan Aarẹ jẹ pe awọn eeyan bii Sunday Igboho le pin Naijiria ati pe pipa Nnamdi Kanu nikan ni ọna abayọ si ọrọ awọn ajijagbara Biafra."














