Anambra election: Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ bí ètò ìdìbò gómìnà Anambra yóò ṣe waye lónìí

Lati ọjọ Ẹti ọjọ karun un oṣu kọkanla ni ibẹru-bojo ti gbalẹ nipinlẹ Anambra ṣaaju eto idibo gomina ipinlẹ naa lonii ọjọ Abamẹta.
Gbogbo ọja, opopona ati ile ifowopamọ lo da paro paro nitori ẹru n ba awọn eeyan lati jade.
Koda, awọn eeyan kan sa kuro nipinlẹ Anambra lati sa asala fun ẹmi wọn nitori wọn ko mọ ohun to le ṣẹlẹ lasiko eto idibo.
- Kí ló so Yemi Osinbajo pọ̀ mọ́ ilé alájà púpọ̀ tó dà wó ní Eko?
- Ọwọ́ Amotekun tẹ ọ̀dọ́ 18 tó rìn gbéregbère wọ Akure láti òkè ọya
- Ẹ̀kùn Àríwá pahùndà, ó fẹ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yà míì láti yan ààrẹ
- Kókó méjìlá nípa ìgbé ayé Femi Osibona
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- Ọ́dọ́kùnrin 18 láti òkè ọya pẹ̀lú ohun ìjà olóró dojú ìjà kọ Àmọ̀tẹ́kùn l'Ondo
- Gómínà díbọn lọ ilé ìwòsàn, òṣìṣẹ ìlera tó gba rìbá N10,000 wọ gàù
Ọpọ eeyan ni wọn ri ni ibukọ nibi ti wọn ti n wọ ọkọ lọ si ipinlẹ Enugu, Delta. Edo, nigba ti awọn mii n lọ si ipinlẹ Abia.
Ọkan lara wọn to sa lọ si ilu Asaba nipinlẹ Delta ni oun ti fẹ lọ fori pamọ titi di igba ti eto idibo naa yoo fi tan.
Ẹlomiran tiẹ sọ pe ọkan oun ko balẹ lati duro si Awka ti ṣe olu ilu ipinlẹ Anambra lasiko idibo, o ni Enugu ni oun mori le.

Oríṣun àwòrán, INEC
Ẹnikan ti ko darukọ ara fawọn akọroyin ni ko si ẹni to fẹ ku lo jẹ kawọn eeyan maa kuro ni Anambra ṣaaju eto idibo gomina.
O ni ẹgbẹ IPOB lo jẹ ki onikaluku maa bẹru pẹlu ohun ti wọn n ṣe nilẹ Igbo.
Ohun to jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan ni pe ẹgbẹ IPOB ti fagile ofin konle-o-gbele to kede ṣaaju eto idibo ọhun eyi to le maa mu awọn eeyan bẹru.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn agbofinro ẹgbẹrun lọna mẹrinlelọgbọn ni yoo mojuto eto idibo naa ki abo to peye le wa.

Ẹgbẹ awọn agbaagba nilẹ Ibo, Ohanaeze Ndigbo naa parọwa si awọn eeyan ipinlẹ Anambra lati jade dibo lonii lai bẹru.
Amọ, awọn kan ni aijade awọn eeyan ipinlẹ naa nii ṣe pẹlu bi ijọba ṣe kede ọjọ meji gẹgẹ bi ọjọ isinmi lati gbaradi fun eto idibo gomina tuntun ipinlẹ Anambra.
Ọpọ eeyan lo ti ra ounjẹ sile ṣaaju eto idibo ki wọn le maa ri nkan ninu ile wọn ti wọn ko ba jade lasiko idibo.
Awọn eeyan tiẹ sọ pe ẹru n ba awọn pẹlu bi awọn ẹṣọ eleto abo ti pọ nipinlẹ Anambra tawọn ti ibọn ati oriṣiiriṣii ohun ija oloro lọwọ wọn.
















