Ondo Amotekun: Kí ni ọ̀dọ́ àríwá 18 tó dirá ìjà ń wá l‘Ondo, tí wọn fi dojú ìjà kọ Àmọ̀tẹ́kùn?

Aworan nkan ija oloro

Oríṣun àwòrán, Ondo Amotekun

Ọrọ ipenija aabo paapa ni ilẹ kaarọ o jiire lo mu ki awọn Gomina panupọ lati ṣe idasilẹ ikọ alaabo Amọtẹkun.

Igbesẹ naa ti wa n so eso rere bayi pẹlu bi Amotekun ipinlẹ Ondo ti ṣe n koju awọn to n wa lati ita wa da omi alaafia ilu ru.

Ninu iṣẹ ti wọn ṣe taa ri to gbọngbọn leleyi ti wọn ti mu awọn ọdọkunrin mejidinlogun kan to dira ija wa lati ariwa Naijiria si ipinlẹ naa.

Ọga ikọ Amọtẹkun Oloye Adeleye Olusanyero sọ fun BBC Yoruba pe loru Ọjọbọ lawọn ikọ Amọtẹkun ṣalabapade awọn ọdọ yi nigba ti wọn fẹ wọ Ondo.

O ni awọn gbiyanju lati da wọn duro ṣugbọn kaka ki wọn duro, niṣe ni wọn fi ọkọ wọn gun ori igi tawọn fi dina ti wọn si fere ge.

Aworan nkan ija oloro

Oríṣun àwòrán, Ondo Amotekun

O ni koda wọn doju ija kọ awọn nipa yinyin ibọn lu awọn ṣugbọn awọn pada ribi mu wọn.

''Ni nkan bi kilomita mejilelogoji si Akure la ti pade wọn lỌjọbọ. A le wọn titi de ilẹ Oluji nibi ti ọwọ ti pada tẹ wọn''

Aworan nkan ija oloro

Oríṣun àwòrán, Ondo Amotekun

Adeleye sọ pe nigba tawọn fọrọ wa dirẹba wọn lẹnu wo, o ni ẹni to ni koun gbe wọn wa ti ko awọn eeyan naa ati ẹru s'ọkọ ki oun to de idi ọkọ.

''Wọn kan ni ki n wa gbe wọn lọ si Ondo ni,mi o mọ wọn ri tabi nkan ti wọn gbe sọwọ'' ni alaye ti dirẹba naa ṣe fun ọga Amọtẹkun.

Amọ ọga Amọtẹkun ni awọn ko gba arakunrin naa gbọ rara.

Ninu awọn kan ti wọn ba lọwọ wọn ni ọta ibọn, ibọn atọwọda ati ọpọlọpọ ọbẹ.

Aworan nkan ija oloro

Oríṣun àwòrán, Ondo Amotekun

Wọn ko ti sọ nkan ti wọn fẹ fi nkan ija yi ṣe tabi ibi ti wọn ti ran wọn wa.

Ọga Amtẹkun ṣalaye pe iwadii ṣi n lọ lọwọ ati pe bi awọn ba pari awn yoo ko wọn lọ si ileẹjọ.

''Ofin to da Amọtẹkun silẹ fun wa lagbara lati ṣe iwadii ti wa lori awọn taa ba ri pe wọn wu iwa ọdaran.''

''A fẹ ki araalu fọkanbalẹ pe digbi la wa lati koju awọn to ba fẹ da omi alaafi ilu ru.Iru rẹ ko ṣẹṣẹ maa waye. A o ni mikan lati koju wọn''

Ni nkan bi ọjọ meloo kan ni BBC jabọ pe Amọtẹkun mu awọn ọdọ mejidinlogun kan lati ariwa Naijiria ti wọn rin irin regberegbe.

Bi awọn wọn yi ko ṣe ri alaye ṣe lori nkan ti wọn wa ṣe, Amọtẹkun fawọn le Miyetti Allah lọwọ ti wọn si fi wọn le ọkọ pada si oke ọya.