Herbalist kills Baby for Ritual: Oníṣègùn pòórá mọ́ àwọn ọ̀dọ́ tó ń lù ú lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, UNUNUMA BIDEMI EDWARD ODOI
Ọjọ keji, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 yii ni awọn ọdọ kan lagbegbe Eduoha, ni ijọba ibilẹ Guusu Ahoada, ni Rivers ke gbajare pe ọwọ awọn tẹ oniṣegun kan, ti wọn fẹsun kan pe o sin ọmọ jojolo laaye.
Gẹgẹ bii ohun ti awọn oṣojumikoro sọ, ọkunrin ọmuti kan to lọ ṣẹyọ ninu igbo lo ka afurasi oniṣegun naa, nibi to ti n sin ọmọ jojolo naa ti iye ọjọ ori rẹ ko tii ju oṣu mẹta lọ.
Iroyin ni oniṣegun naa n ka ọfọ ati ayajọ le ọmọ ọhun lori bo ṣe n sin, ṣugbọn ọmuti naa wọ jade ninu igbo ọhun, o si ke ibosi le lori.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọta ìbọn ń já bọ́ láti òrùlé ilé Banji Akintoye
- "Pásítọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti lébìrà 18 tó kó wá láti Ibafo sì wà lábẹ́ ilé Ikoyi "
- Tinubu, àtúntò Nàíjíríà ni ko wá ná, ko tó du ipò ààrẹ - Pa Adebanjo
- "Bí ọmọ rẹ kò bá gba First Class ní fásitì Ibadan, máṣe yọjú fún ayẹyẹ ìkẹkọọjáde"
- Buhari ti já kulẹ bí ìbò Anambra bá forí ṣánpọn - Onímọ òṣèlú
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ó fi sísọ́ọ̀sì gún aya rẹ̀ pa
Nnkan bii aago kan ọganjọ oru ni iṣẹlẹ naa waye gẹgẹ bii ohun ti a gbọ.
Lasiko ti awọn ọdọ ilu bẹrẹ si n da ibeere bo afurasi naa, ni wọn wọ lọ sile rẹ lati wo awọn ohun to wa nibẹ amọ iroyin ko to afojuba.

Oríṣun àwòrán, Ununuma Bidemi Edward Odoi
Lara awọn ohun ti wọn ri ninu ile rẹ ni oniruru ọ̀bẹ, apakan ile ọhun ni awọn ṣẹkẹṣẹkẹ nla, to fi mọ awọn aga ti wọn kan mọlẹ.
Oṣojumokoro kan sọ fun BBC pe ọkunrin naa kii ṣe ajoji ladugbo naa, nitori ibẹ lo kọ ile si, ṣugbon ile naa ni ogiri to ga pupọ ti ẹnikẹni ko le ri ohun to ba n ṣẹlẹ ninu rẹ.
- Ìjọba Ethiopia figbe ta pe ogun ń bọ, ó kéde ìlú kò fara rọ
- Mọ̀ sì nípa Femi Osibona tó ni ilé alájà 21 tó wó ní Ikoyi
- Àsìta ìbọn bá àkẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan, bí ọ̀rọ̀ ṣe wáyé rèé
- Mo fẹ́ dákú níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún mi - Salawa Abeni
- Ọwọ́ Amotekun tẹ ọ̀dọ́ 18 tó rìn gbéregbère wọ Akure láti òkè ọya
Awọn eeyan adugbo naa tun sọ pe afurasi ọhun ni ọmọ ati aya ti wọn dijọ n gbe papọ.
Iroyin ni bi wọn ṣe wọ inu ile naa, ni wọn bẹrẹ si n lu ni ilu bara nitori awọn ohun ti awọn eeyan ri nibẹ, ṣugbọn ṣadede lo poora laarin wọn bi wọn ṣe n na lọwọ.
Eredi ree ti awọn eeyan naa ṣe sọ ina sile ọhun.

Oríṣun àwòrán, UNUNUMA BIDEMI EDWARD ODOI
Aworan awọn eeyan ti wọn fi agadagodo ti pa
Oriṣiriṣi aworan awọn eeyan lo wa ninu ile ọkunrin naa, bii ọkunrin, obinrin atawọn ọmọde.
Lara awọn aworan naa ni wọn kan si ara ogiri, nigba ti wọn so awọn mii mọ agadagodo, ti wọn si ti mọ inu ẹwọn.
Awọn ọdọ to ya bo ile naa tun foju ganni oniruru oogun abẹnugọngọ, ki wọn to sọ ina si.
Ọkan lara awọn oṣojumokoro naa ni "Awọn eeyan kan ri aworan awọn mọlẹbi wọn kan nibẹ bo tilẹ jẹ pe awọn mọlẹbi wọn naa ti dagbere faye."
"Mo ri awọn eeyan ti mo mọ nibẹ, mo tilẹ pe ẹni naa, ti mo si lọ fun ni aworan ọhun, ṣugbọn ẹsẹ ti n dun ẹni naa fun awọn akoko kan."
"Mo ri aworan ti wọn de ṣẹkẹṣẹkẹ mọ ti wọn tun fi sinu ẹwọn iru eyii ti wọn maa n tọju aja si."

Agbegbe ti awọn babalawo pọ si:
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to tii le sọ ni pato irufẹ eeyan ti afurasi naa, Mike Indiana jẹ, iroyin ni awọn babalawọ ati onịsegun wọpọ lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Ẹnikan tilẹ sọ fun BBC pe ọpọ awọn olugbe agbegbe naa lo gba lati maa fi ọrọ to awọn oniṣegun ni agbegbe naa leti, kaka ki wọn gbe ẹjọ lọ si agọ ọlọpaa.
Ẹwẹ, ileẹṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ni awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, amọ wọn n reti alaye lẹkunrẹrẹ lati ọọfisi ẹka ti Ahoada.



















