Domestic Violence in Nigeria: Ọkùnrin tó fi sísọ́ọ̀sì gún aya rẹ̀ pa kó sí gbaga ọlọ́pàá l‘Ogun

Mojiyagbe Olamilekan to fi sisọsi pa aya rẹ

Oríṣun àwòrán, Ogun Police Command

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ okunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Mojiyagbe Olamilekan, lori ẹsun pe o gun iyawo rẹ pa.

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ naa, Abimbola Oyeyemi fi lede, o ni agbegbe Oke ola, ni Ode Remo ni afurasi naa ti fi sisọọsi gun aya rẹ pa.

Oyeyemi sọ ninu atẹjade naa pe ọwọ awọn tẹ afurasi ọhun lẹyin ti awọn eeyan adugbo to n gbe, ke gbajare si awọn ni nnkan bii ago mẹta ọsan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "Ohun ti a gbọ ni pe ọkunrin ọhun ti aya rẹ mọ inu yara to si bẹrẹ si n lu ni ilu bara, ariwo rẹ ni awọn eeyan adugbọ gbọ ti wọn fi kan si ileeṣẹ wa."

"Gbogbo igbiyanju awọn ara adugbo lati ri pe o ṣi ilẹkun yara to ti aya rẹ naa mọ lo ja si pabo."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Herbalist: Agbófinró mẹ́fà ló wọ́lé wá gbé ọmọ mi láì mọ́ ibi tó wà

Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe, ọga ọlọpaa Ode Remo ko awọn oṣiṣẹ rẹ lọ sile ti iṣẹlẹ naa ti waye, wọn si fi agidi ja ilẹkun afurasi naa ṣugbọn ọrọ naa ti bọ sori, nitori inu agbara ẹjẹ ni wọn ba obinrin ọhun.

Oyeyemi ni lẹyin naa ni wọn gbe obinrin naa digba-digba lọ sile iwosan kan ni Isara Remo lati doola rẹ ṣugbọn o ti padanu ẹmi rẹ nigba ti wọn yoo fi de ile iwosan ọhun.

Lẹyin naa ni wọn fi ṣikun ofin mu afurasi naa ti wọn si fi si atimọle, nigba ti wọn gbe oku aya rẹ lọ sile igbokusi lati tọpinpin ohun to mu ẹmi rẹ lọ.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ ki wọn gbe ẹjọ naa si ẹka ti wọn ti n ṣe iwadii ẹsun ipaniyan fun iwadii to peye.

Bankole tun ni afurasi ọhun gbọdọ foju bale ẹjọ ni kete ti iwadii naa ba ti pari.

Àkọlé fídíò, Olugbon Twins: Ọba Alao àti Olorì rẹ̀ bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró lẹ́ni ọdún 53