Bank Fraud: Ọ̀gá báńkì rí ẹ̀wọ̀n ọdún 18 he lórí jìbìtì N219m owó oníbàárà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
A se ẹni ti a gboju oku le, ko jọ ẹni agba, abi ki ni ka ti pe ẹni ti a fẹtin ti, to fi ẹgun sọwọ, ẹni ta ni ko fẹ ni loju, to fi ata sẹnu.
Ọga banki tẹlẹ kan ree, Olìver Anidiobi, to ti di ero ẹwọn lori pe o lu awọn onibaara ni jibiti okolerugba o din ẹyọ kan miliọnu naira, N219m.
Anidiobi, ti ajọ EFCC gbe lọ sile ẹjọ ni adajọ C.O. Ajah, dajọ ẹwọn ọdun mejidinlogun fun niluu Enugu lori ẹsun ole jija ati yiyi iwe owo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo fẹ́ dákú níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún mi - Salawa Abeni
- Àwọn adarí iléẹ̀kọ́ wọ gàù fún gbígba owò lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àìtọ́
- Àwọn agbébọn kọlu ilé adarí Ilana Omo Oodua Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye l'Ado-Ekiti
- Èèyàn ogún ló ti sọ ẹ̀mí nù nínú ilé alájà 21 tó wó ni Ikoyi - NEMA
- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Iree Poly pọ ẹ̀jẹ̀ àti itọ́ kó tó kú lẹ́yìn tó dé láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀
- Àṣírí ti tú,kà nípa bí ìyàwó ilé ṣe lẹ̀dí àpọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ jí ọkọ rẹ̀ gbé
- A gbọ́ ohùn bí àwọn ènìyàn tó há sí abẹ́ ìlé alájà 21 ṣe ń kérọrà fún ìrànwọ́ – NEMA
- Wòlíì kan fún òṣèré tíátà ní miliọnu mẹ́fà náírà láti fi tọ́jú àìsàn rẹ̀
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ló mú kí ìjọba gbógun ti orísùn ọrọ̀ ajé mi - Yomi Fabiyi figbe ta
- Fulani darandaran kò ṣe lè ní Kwara, wọ́n pọ̀ ju ọmọ onílùú lọ
Ajọ EFCC to jẹ olupẹjọ gbe Anidiobi lọ ile ẹjọ lọjọ keje oṣu karun ùn ọdun 2019 lori ẹsun pe o lo ipo rẹ, lati ri pe banki olokoowo kekeke OHHA kan san N219m ni orukọ rẹ.
Wọn ní Anidiobi gbe owo naa sí asunwọn ikowosi ọlọjọ pipẹ (fixed deposit account) ṣugbọn o lu jibiti owo naa lati lo o fun ra rẹ.
Ile ẹjọ fidi rẹ múlẹ pe, ọga banki naa kọ ile marun un, o sí tun ra ọpọ ilẹ si ọna mọrosẹ ilu Enugu si Port Harcourt.
Bakan naa ni wọn ní ọga banki tẹlẹ ọhun tun n kọ ile mii lọwọ niluu Enugu.
Ile ẹjọ tun fidi rẹ múlẹ pe o tun fi N65m ṣe owo s'ogun dogoji ti wọn pe ni "Let's Partner with You" ti ọkunrin kan ti wọn pe ni Patrick Nwokike jẹ alakoso rẹ.
Adájọ Ajah sọ pe Anidiobi kó tako ajọ EFCC lori gbogbo ẹsun ti o fi kan an.
Adájọ ni "o túmọ si pe otitọ ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Anidiobi tori ko ri ariwisi kankan si ẹsun ti wọn fi kan an.
Awọn ẹri ti EFCC mu wa sile ẹjọ fidi múlẹ to lati dajọ."
Bayii ni ile ẹjọ ṣe dajọ ẹwọn ọdun mejidinlogun fun Anidiobi.
Adajọ tun pàṣẹ pe ki wọn lọ tá gbogbo dukia ti Anidiobi fi owo naa ra, ki wọn sì da owo ti wọn ba ri níbẹ pada fun banki olokowo kekeke OHHA.



















