Kwara: Àwọn adarí iléẹ̀kọ́ wọ gàù fún gbígba owò lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àìtọ́

Oríṣun àwòrán, NUT
Ijọba ipinlẹ Kwara ti fi imu awọn adari ileẹkọ girama kan fọnrin lori ẹsun pe wọn n gba owo ti ijọba ko fi ọwọ si lọwọ awọn akẹkọọ.
Iroyin ni igbeṣẹ ijọba yii ko ṣẹyin bi awọn obi kan ṣe lọ fi ẹjọ sun ni ẹka ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ eto ẹkọ, Ministry of Education and Human Capital Development, ni ilu Ilorin.
Wọn fi ẹsun kan awọn adari ileẹkọ naa pe wọn n gba awọn owo to yatọ si owo PTA ti ijọba fi ọwọ si ki wọn ma a gba lọwọ awọn akẹkọọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo fẹ́ dákú níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún mi - Salawa Abeni
- Àwọn agbébọn kọlu ilé adarí Ilana Omo Oodua Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye l'Ado-Ekiti
- Èèyàn ogún ló ti sọ ẹ̀mí nù nínú ilé alájà 21 tó wó ni Ikoyi - NEMA
- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Iree Poly pọ ẹ̀jẹ̀ àti itọ́ kó tó kú lẹ́yìn tó dé láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀
- Àṣírí ti tú,kà nípa bí ìyàwó ilé ṣe lẹ̀dí àpọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ jí ọkọ rẹ̀ gbé
- A gbọ́ ohùn bí àwọn ènìyàn tó há sí abẹ́ ìlé alájà 21 ṣe ń kérọrà fún ìrànwọ́ – NEMA
- Wòlíì kan fún òṣèré tíátà ní miliọnu mẹ́fà náírà láti fi tọ́jú àìsàn rẹ̀
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ló mú kí ìjọba gbógun ti orísùn ọrọ̀ ajé mi - Yomi Fabiyi figbe ta
- Fulani darandaran kò ṣe lè ní Kwara, wọ́n pọ̀ ju ọmọ onílùú lọ
Ijọba ni awọn pe awọn adari ileẹkọ naa ki wọn le wa wi tẹnu wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn, ko le jẹ ẹkọ fun awọn to ku lati yee gba owo ti ko yẹ lọwọ awọn akẹkọọ.
Kọmiṣọnna fun eto Eko nipinlẹ naa, Hajia Saádatu Modibbo Kawu ni awọn ṣe ipade pajawiri pẹlu awọn adari ileẹkọ naa, paapaa awọn ti wọn tọka si pe wọn n gba owo aitọ lọwọ awọn akẹkọọ.
''Awọn obi kan ti wa fi ẹjọ awọn adari ileẹkọ sun pe wọn n gba owo ju owo PTA ti ijọba fọwọ si ati awọn nkan mi ti ijọba ko lọwọ si.''
Ninu ọrọ rẹ, Kawu ni ijọba ko ni dakẹ lroi iṣẹlẹ ibanilorukọ jẹ ni awọn ileẹkọ ijọba.
O fikun pe ijọba n ṣiṣẹ takun takun lati ri pe aye rọrun fun awọn obi ati awọn akẹkọọ nipa owo sisan ni awọn ileẹkọ ijọba nipinlẹ naa.
Kọmiṣọna naa ni awọn adari ileẹkọ naa fẹ doju ijọba gomina Abdulrahman Abdulrazaq bole ni ọna eto ẹkọ.
Awọn ileẹkọ ti wọn fẹsun kan naa ni UBE Ita Ayisa, UBE Olulande, United Secondary School, Taiwo Isale, United UBE, Taiwo Isale ati Oke-Aluko Junior and Senior Secondary School, in ilu Ilorin.
Awọn to ku ni UBE Ganmo, Senior Secondary School, Ganmo and Senior Secondary School, Amoyo, in ijọba ibilẹ Ifelodun ni ipinlẹ Kwara.


















