Ikoyi Collapse Building: Ọ̀pọ́ ẹ̀bí àwọn tó sì wà ní abẹ́ ilé tó wó ló ti ń fẹ̀hónúhàn pé iṣẹ́ náà ń falẹ̀ jù

Awọn eeyan to wa nibi ile to dawo

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ó kéré tan ènìyàn ogún ni wọ́n ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n sọ ẹ̀mí nù nínú ilé alájà mọ́kànlélógún tó dàwó ni Ikoyi ní ìlú Eko.

Nǹkan bí aago méjì ọ̀sàn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣe iṣẹ́ ilé lọ́wọ́.

Sáájú ni ìròyìn ti fi hàn pé kò dín ni èèyàn mẹ́wàá tó tó ti kú tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mííràn sì ha sí abẹ́ ilé nàá tó fi ma àdári ilé iṣẹ́ Fourscore Heights Limited Femi Osibona tó ni ilé náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alábojútó iwọ-òòrùn guusú fún NEMA Ibrahim Fariloye sọ lọjọ́ Iṣegun pe okú ènìyàn ogún ni wọ́n ti kó jáde, tó fi mọ ti amúgbálẹ́gbẹ́ Femi Osibona to ni ilé náà, ti wọ́n sì ti wú okú wọ́n.

Kọmísọ́nà ọlọ́pàá ní ìpińlẹ̀ Eko Hakeem Odumosu ní nǹkan bí aago mẹ́jọ alẹ́ ọjọ́ Isẹ́gun náà sọ pé okú ènìyàn ogún ni wọ́n ti rí yọ.

Àkọlé fídíò, Ikoyi Collapsed Building: Bí ilé alájà mọ̀kànlélógún ṣe dà wó lulẹ̀ ní Ikoyi, l‘Eko rèé

Mẹ́sàn-án ni àwọn tó wà láàyè tí wọn si ti gbe lọ fun ìtọ́jú.

Ìròyin sọ pé mẹ́tà nínú àwọn tó jẹ́ Ọlọ́run nípè ni wọ́n ti yọ̀nda fún àwọn ẹbí wọn, nígbà tí wan gbé àwọn tó kù lọ sí ilé ìwòsàn gbogbonìṣe Lagos Island Marina.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ́ ẹ̀bí àwọn mííràn tó sì wà ní abẹ́ ilẹ̀ ló ti ń fẹ̀hónúhàn pé, iṣẹ́ náà tí n falẹ̀ jù.

Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀bí atí olùbádarò rọ àwọn oníṣẹ́ pàjáwìrì láti gba àwọn lááyè láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nibi iṣẹ́ náà kí àànfani le wà fún àwón tí yóò tún yè.

Bákan náà ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n kò gba àwọn láàye láti yẹ àwọn ènìyàn wò láti mọ okú wọn.

Iroyin sọ pé, ọmọbinrin kan tó jẹ́ agùnbánirọ̀ tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ni Zainab, náà wà lábẹ́ ilé náà.

Àkọlé fídíò, Olugbon Twins: Ọba Alao àti Olorì rẹ̀ bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró lẹ́ni ọdún 53