Failed Kidnap attempt: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ìyàwó ilé tó gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan láti jí ọkọ rẹ̀ gbé

Oríṣun àwòrán, Ogun Police Command
Ẹhinkunle lọta wa ile bayi ni aṣeni n gbe.
Bẹẹ lọrọ yi jọ nigba ti ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ iyawo ile kan Memunat Suleman nibi toun ati awọn ajinigbe ti n gbimọran lati ji ọkọ rẹ gbe.
Gẹgẹ bi atẹjade lati ọwọ alukoro ọlọpaa,Abimbola Oyeyemi ti ṣe sọ, adugbo Papa/Itori ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn olubi yi.
Koda lori alupupu lawọn ọlọpaa ti ri awọn ọkunrin mẹta Olayinka Lawal, Asungba Nura ati Usman Oluwatoyin ti Memunat gbe iṣẹ fun pe ki wọn ji ọkọ rẹ gbe.
Awọn ọlọpaa furasi irin ẹsẹ awọn mẹtaa wọn yi ti wọn si da wọn duro.
Lẹyin ifọrọwanilẹnuwo ati ayẹwo wọ, wọn pada ri ada ati okun lọwọ wọn.
Abalọ ababọ awọn afurasi yi jẹwọ fun ọlọpaa pe arabinrin kan Memunat Salaudeen lo fun awọn ni ẹgbẹrun mẹjọ Nairia lati fi ra okun ati ada.
Wọn tẹsiwaju pe arabinrin to jẹ nọọsi sọ pe kawọn lọ gọ pamọ soju ọna wi pe oun yoo tan ọkọ rẹ wa tawn yoo si jin gbe.
O ni ọgbọn yi nikan loun le lo lati le fi ri owo gba lọwọ ọkọ oun nitori o ya ahun toun ti pe owo wa lọwọ rẹ.
Ka ma fa ọrọ gun pupọ, awọn ọlọpaa foju alaje Memunat kan onisọ awọn ajinigbe yi to si pada wa jẹwọ pe oun mọ si ọgbọn ati ji ọkọ rẹ gbe.
O jẹwọ fawọn ọlọpaa lootọ to si ni ko si ọna mi toun fi le ri owo gba lọwọ ọkọ oun.
Kọmisana ọlọpaa Ogun ti ni ki wọn gbe wọn lọ si ẹka to n gbogun ti ijinigbe ki iwadii to yẹ si waye.












