Uniabuja Abduction: : Àrá àdúgbò ní aago kan òru ní agbébọn ya wọ fásitì Abuja lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, wọ́n jí olùka àti akẹ́kọ̀ọ́ lọ

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn agbebọn ti kọlu ilegbe awọn oṣiṣẹ fasiti ìlú Abuja, ti wọn si gbe eeyan mẹfa lọ, ni owurọ kutu ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejì, oṣu Kọkanla.

Awọn ara adugbo sọ pe ni nkan bi aago kan oru ni awọn agbebọn naa wọ inu ọgbà naa, ti wọn si ṣíṣẹ fun bi wakati kan.

Olukọ kan sọ fun BBC pe olukọ mẹta ati ọmọ wọn meji, to fi mọ oṣiṣẹ fasiti naa kan, ni wọn ji gbe lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmisana ọlọpaa nilu Abuja, Babaji Sunday fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita.

O ni awọn ọdaran naa kọlu ibi ti awọn oṣiṣẹ UNIABUJA n gbe ni agbegbe Giri, ni ijọba ibilẹ Gwagwalada nilu Abuja, ti wọn si ji eeyan mẹfa gbe lọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Aide: Omiyale ni DSS rọ̀jọ̀ ibọn sí Igboho, wọ́n wá pa ni àmọ́ ó bọ́

Ọgbẹni Sunday sọ pe awọn agbebọn naa salọ ni kete ti wọn gburo àwọn oṣiṣẹ eleto aabo to jẹ apapọ àwọn ọmọ ologun ati ọlọpaa to lọ sibẹ lati daabo bo àwọn araalu.

Bakan naa lo sọ pe awọn oṣiṣẹ alaabo ti n sisẹ pẹlu ara ilu, lati le doola awọn eeyan ti wọn ko lọ.

Ẹ̀wẹ̀, agbenusọ fasiti naa, Habib Yakoob sọ pe awọn ko ti le fidi orúkọ awọn ti wọn ji gbe mulẹ.