Ooni: Ọba Ogunwusi gbarata lórí bí ọ̀pọ̀ ojú ọ̀nà ní Ile Ife ṣe dẹnu kọlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ooni Ile Ife
Ooni ti Ile Ifẹ, Ọba Adedeye Enitan Ogunwusi ti fi aidunnu rẹ han si bawọn oju ọna to jẹ tijọba apapọ ati tipinlẹ to wọ Ile Ifẹ se dẹnu kọlẹ.
Ọba Ogunwusi ni ko dara to bi ijọba ipinlẹ Osun ati ijọba apapọ ṣe fi awọn opopona naa silẹ lai se atunse wọn pẹlu bi o ṣe bajẹ naa.
Ọọni sọ ọrọ yii ni Ile Ifẹ lasiko ti wọn n ṣi oju ọna ọja Odo-Ogbe (Ọja tuntun) ni Ile-Ifẹ, eleyii ti Sẹnetọ Babajide Omoworare Ogunwusi ṣe agbatẹru rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ọ̀pọ̀ ajìjàgbara Yorùbá Nation ló ń tan aráàlú jẹ láì sọ òtítọ́ - Seyi Makinde
- Kí ló mú Lizzy Anjorin ṣe àyẹ̀wò DNA ọmọ rẹ̀?
- Ẹ wò àsọtẹlẹ tí Odumakin sọ nípa ìbejì tí ìyàwó rẹ̀ bí loṣù mẹ́fà tó jáde láyé
- Ohun tó gbé mi lọ sọ́dọ̀ Buhari lọ́jọ́ Àìkú rèé - Tinubu
- Ọwọ́ tẹ èèyàn mẹ́ta tó gbé òògùn olóró sínú ọṣẹ dúdú
- Agbébọn kọlu ṣọ́ọ́ṣì, èèyàn méjì kú, wọ́n kó ọ̀pọ̀ olùjọ́sìn lọ
- Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
- Gómìnà díbọ́n bíi aláìsàn lọ ṣèwádí aṣemáṣe àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn, ọ̀rọ̀ kọ sísọ
- Ó ṣèèsì bọ́ sí wọ́n lọ́wọ́ ní, APC kò ṣetán láti ṣe àkóso ìjọba ní 2015 - Atiku
- Má ṣé wàhálà wàásù fún mi, mo ti yọ ìdájọ́ ọ̀run kúrò lọ́rọ̀ mi - Bobrisky
Ninu atẹjade ti adari ikọ iroyin fun Ooni fi lede lo ti ni iru iya to n jẹ ilu Ile Ifẹ ko tọ si bẹẹ.
O ni ijọba kọ lati ṣe awọn oju ọna yii, bakan naa ni wọn kọ fun awọn araalu lati tun awọn opopona ṣe fun ara wọn.
''Ohun ti a n gbọ ni pe oju titi ijọba ni nitori naa a gbọdọ duro de ijọba lati ṣe awọn oju ọna yii.''
''Amọ wi pe ijọba ko le ṣe awọn iṣẹ akanṣe yii fun ara wọn ni gbogbo igba, ti wọn si nilo iranwọ nigba miran''
''Nitori naa ki ijọba ṣe awọn eto kan ti yoo fun awọn araalu ni anfaani lati tun awọn ọna yii ṣe.''
''A o wa awọn eniyan to kunjuwọn ni awujọ wa, lati ṣe awọn oju ọna yii, ki ijọba si san pada fun wọn nipa sisan owo ori wọn''
Ọọni parọwa si ijọba pe ki wọn fun awọn eniyan ni anfaani lati tun awọn opopona yii ṣe, boya wọn ko ni ṣe awọn iṣẹ yii kunjuwọn.

Oríṣun àwòrán, Ooni Ile Ife



















