Gómìnà díbọ́n bíi aláìsàn lọ ṣèwádí aṣemáṣe àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn, ọ̀rọ̀ kọ sísọ

Gomina ati osisẹ ile iwosan

Oríṣun àwòrán, Meru FM 88.3 Official/Facebook

Gomina ipinlẹ kan to fi aṣiri ipo rẹ pamọ ls si ile iwosan kan ṣugbọn ohun to ba pade nibẹ kọja sisọ. Muthomi Njuki

Gomina ipinlẹ Tharaka Nitu, Arakunrin Muthomi Njuki ṣe abẹwo si ileewosan kan. Ko fẹ ki wọn mọ pe oun lẹni to wa bẹ wọn wo lo mu ki Muthomi wọ aṣọ agbojo kan pẹlu ibomu ati fila eleyi ti yoo mu ko ṣoro fun ẹnikẹni lati daa mọ.

Gbogbo awọn to wa nile iwosan naa ni ko da gomina agbegbe naa to wa bẹ wọn wo mọ, ṣe awọn agba bọ wọn ni irinisi ni isọnilọjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eredi igbesẹ gomina Muthomi Njuki ni lati tu aṣiri ihuwasi awọn dokita ati nọọsi ileewosan si iṣẹ ti wọn n gba owo oṣu fun.

Iroyin sọ pe, oniruuru ẹhonu ati iwe ifisun lawọn araalu ti kọ sii lori ohun ti oju wọn n ri nigba ti wọn ba lọ si ile iwosan.

Ọpọ awọn araalu ni agbegbe naa niwọn n fi apa janu pe nigbakugba ti awọn ba ti lọ si ileewosan naa lo maa n gba awọn dokita ati nọọsi ibẹ lọpọ akoko ki wọn to da awọn lohun.

Àkọlé fídíò, Kiki Osinbajo: T;o bá yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, máa gbìyànjú láti da padà

Bakan naa ni wọn tun n kerora pe wọn tun lee ma da awọn lohun, ki wọn ni ki awọn lọ pada lọjọ miran.

Ibi aye awọn to wa fun iwosan ni gomina Muthomi joko si fun ọpọlọpọ akoko, nibi to ti n wo iṣesi awọn dokita ati nọọsi ileewosan naa.

Nigba to pẹ, lo dide to si yọ gbogbo ohun to wọ fi bo aṣiri idanimọ rẹ kuro.

O da wọn lẹkọ lori ihuwasi iṣẹ ẹni, to si gba wọn nimọran pe ki wọn rii daju pe wọn n ṣe iṣẹ ti wọn n gbowo oṣu fun pẹlu ibẹru Ọlọrun.

Gomina joko nile iwosan

Oríṣun àwòrán, Meru FM 88.3 Official/Facebook