Man Kills Wife With Snake in India: Iléẹjọ́ dá ẹ̀wọ̀n gbére fún ọkùnrin tó fi ejò pa aya rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arakunrin kan to fi ejo ṣa iyawo rẹ pa ti gba idajọ ilọpo meji ẹwọn gbere.
Laipẹ yii ni adajọ gbe idajo to ṣọwọn yii kalẹ fun Suraj Kumar, ti wọn lo jẹbi ṣiṣe iku pa iyawo rẹ.
Awọn akọroyin gbiyanju lati tu iṣu de isalẹ koko lori idajọ yii ati iwadii alagbara to waye saaju idajọ naa.
- Ohun márùn ún tí ejò ń jẹ
- Ejò bu abóyún jẹ nílé ìyàgbẹ́, ó kú pẹ̀lú oyún oṣù mẹ́jọ ní Kaduna
- ''Pásítọ̀ ní kí n gbé ọwọ́ lé ǹkan ọkùnrin ọ̀un, ní ejò dúdú bá jádé...''
- Wo oríṣi oúnjẹ márùn ún tí kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn kan fẹ́ràn púpọ̀ ní Nàìjíríà
- Ejò bu ìdí obìnrin kan jẹ nínú ilé ìgbọ̀nsẹ
- Awọn ọmọogun Indonesia n mu ẹjẹ ejo
- Isẹlẹ arigbarimu lori owo to poora waye ni Burundi
- Ejò bu ìdí obìnrin kan jẹ nínú ilé ìgbọ̀nsẹ

Loṣu Kẹrin ọdun to kọja ni Suraj san owo ẹgbẹrun meje rupees owo India ti o sunmọ dọla mejilelaadọrun lati fi ra ejo oloro sebe.
Sebe yii la gbọ pe o jẹ ọkan lara eyi to loro julọ ni agbaye.
Rira tabi tita ejo lodi sofin India tori naa ọna ẹburu ni Suraj fi ra ejo naa lọdọ arakunrin kan to maa n mu ejo laaye, Suresh Kumar nipinlẹ Kerala.
O lu iho si inu ike kan ki ejo naa ba le ribi maa mi, to si gbe lọ si ile.
Bi o ṣe fi ejo pa iyawo rẹ:
Ọjọ mẹtala lẹyin ti o ra ejo yii, Suraj rinrin ajo lọ si ile awọn ana rẹ nibi ti iyawo rẹ Uthra ti n gba itọju lori ejo to san jẹ.
Lọdun meji sẹyin ni wọn pade ara wọn nipasẹ alarinna.
Onikẹkẹ Maruwa ni baba Suraj, ti iya rẹ a si maa ba awọn eeyan tọju ile.

Oríṣun àwòrán, Sreedhar lal
Ọdun mẹta lo wa laarin awọn mejeeji ṣugbọn ọlọrọ ni awọn mọlẹbi Uthra, ta si tun gbọ pe o ni ipenija diẹ nipa ẹkọ kikọ.
Oniṣowo rọba ni baba ọmọbinrin naa, ti iya rẹ si ti fẹyin ti nidi iṣẹ adari ile ẹkọ girama, Principal.
Owo tabua ati awọn nnkan mii ni mọlẹbi Uthra san fun Suraj, gẹgẹ bi owo ori.

Oríṣun àwòrán, Sreedhar lal
Ni India, awọn mọlẹbi obinrin lo maa n ko nkan idana lọ fun ọkọ. Koda wọn tun n fun lowo oṣu ẹgbẹrun mẹjọ rupees lati maa fi tọju ọmọ wọn.
Ọdọ awọn obi rẹ ni Uthra wa lẹyin ti ejo kan san jẹ. O lo ọjọ mẹtadinlọgọjọ nile iwosan to si ṣe iṣẹ abẹ mẹta ọtọọtọ.
Suraj di ejo mu titi to fi san iyawo rẹ jẹ lẹmeeji:
Lalẹ ọjọ Kẹfa oṣu Karun ni awọn oniwadi sọ pe Suraj fi oogun orun sinu ọti ẹlẹrindodo, to si gbe fun iyawo rẹ Uthra lati mu u.
Nigba ti oogun oorun naa ti dahun lara iyawo rẹ, Suraj gbe ejo sebe yii, to si ju u si lara.
Amọ riro ni ti eniyan, sise ni ti Oluwa. Kaka ki ejo naa san iyawo rẹ, n ṣe lo ba tiẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Sreedhar lal
Ẹẹmeeji ọtọọtọ ni Suraj sọ ejo ọhun si aya rẹ lara ṣugbọn ejo naa ko san Uthra rara.
Nigba to ri pe ejo naa ko fẹ da lohun, lo ba fi tipa di ori ejo mu, to si kọ ẹnu rẹ sara Uthra.
Inira to mu ba ejo yii lo mu ki sebe naa san iyawo rẹ lẹẹmeji.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjíròrò tó wáyé láàrín Bola Tinubu àti Igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo, ohun tí a rí gbọ́ nípa rẹ̀ nìyí
- Wo ọ̀nà tí o lè gbà borí àìsàn rọpá-rọṣẹ̀ tó ń pa ọ̀gọ̀rọ̀ lágbáyé
- Omi ìdọ̀tí atí ''biscuit'' la jẹ fún ọjọ́ méje - Àwọn àgùnbánírọ̀ sọ ìrírí wọ́n lọ́wọ́ ajínígbé
- Wo bí àwọn agbófinró ṣe ya bo ilé Onídájọ́ Mary Odili pẹ̀lú àwọn ohun tuntun tó súyọ
- Iléẹ̀kọ́ fásitì OAU ṣí padà lẹ́yìn ikú akẹ́kọ̀ọ́, Aishat Adesina tó fa ìfẹ̀hónúhàn
- A kò ní gbà kí Buhari yá $700m fi pèsè omi fún aráàlú - Ilé Aṣòfin
Oro yii lo ṣokunfa bi iyawo rẹ se ku, ti awọn obi rẹ si ba oku rẹ lori ibusun lowurọ ọjọ Keji.
Bi aṣiri se pada tu ree:
Mọlẹbi jowere lati du ẹmi Uthra ṣugbọn ko ba.
Awọn dokita ile iwosan ni oku rẹ ni wọn gbe de ọdọ awọn.
Isẹlẹ naa ru awọn mọlẹbi loju, ti wọn si ni ki wọn ṣe ayẹwo oku Uthra lati m ohun to se okunfa iru iku to mu lọ.
Ayewo lo fi han pe ejo lo san ọmọ wọn pa, lẹyin iwadii ọlọjọ mejidinlọgọrin, igbẹjọ bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Sreedhar Lal
Ọpọ awọn onimọ ayẹwo ẹjẹ ati dokita to jẹri nile ẹjọ nipa iwadii wọn lori iku to pa Uthra.
Babanbari ni igba ti Suresh to ta ejo oloro fun Suraj jẹ́ri pe lootọ loun ta ejo mejeeji to san iyawo rẹ pa.
Igba yii ni ọrọ wa to niyanju pe ejo alakọkọ to san iyawo rẹ ki wọn to gbe lọ si ile iwosan fun itọju, o lọwọ Suraj ninu.
Ọrọ pọ ninu iwe kobo ṣugbọn lẹyin atotonu lọtun losi,adajọ ran Suraj lọ si ẹwọn gbere onipele meji.

Oríṣun àwòrán, Sreedhar Lal














