NYSC Kidnap: Omi ìdọ̀tí atí ''biscuit'' la jẹ fún ọjọ́ méje - Àwọn àgùnbánírọ̀ sọ ìrírí wọ́n lọ́wọ́ ajínígbé

AGUNBANIRO

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọkan lara awọn agunbanirọ ti wọn jigbe lasiko ti wọn n lọ sinru ilu ti sọ iriri wọn ni panpẹ awọn ajinigbe fun ọjọ meje.

Arabinrin Jeniifer Lorliam to s iriri rẹ ni biscuit, to fi mọ ounjẹ to ti bajẹ ati omi idọti ni wọn fun wọn mu fun ọjọ meje ti wọn fi wa ni panpẹ awọn ajinigbe naa.

Laipẹ yii ni iroyin gbe e pe Lorliam , Joseph Aondona ati ajubanirọ miran to fi mọ araalu mẹrin miran ni awọn agbebọn jigbe ni Ọjọ Iṣẹgun to kọja lọna opopona ipinlẹ Kebbi nigba ti wọn n lọ fun isinru orilẹede fun ọdun kan gẹgẹ bi agunbanirọ.

Lẹyin ti awọn ajinigbe gba miliọnu mẹsan an naira ni wọn ṣẹṣẹ fi wọn silẹ.

Awọn agunbanirọ naa wọ ọkọ to n lọ si Sokoto lati Benue ki awọn agbebọn to ra wọn gba ni ijọba ibilẹ Tsafe ni ipinlẹ Zamfara.

Awọn agunbanirọ yẹ ki wọn wọ ọkọ miran lati Sokoto lọ si Kebbi ti wọn nlọ lati lọ sin orilẹede wọn.

Lasiko ti agunbanirọ naa n sọ iriri rẹ, o ni asiko ti dirẹba ọkọ awọn n wa ọna lati yago fun awọn koto to wa ni ọna, ni awọn agbebọn naa bẹrẹ si ni yin ibọn, ti wọn si jade lati inu igbo.

''Ọpọlọpọ awọn agbebọn naa wọ aṣọ ọmọogun, ti wọn si ni ki a bọ silẹ ninu ọkọ ki a wọ igbo lọ.''

Àkọlé fídíò, Oyo Jailbreak: Wo ọṣẹ́ tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n Abolongo ṣe fáwọn ará Oyo àti bí wọn ṣe rí wọn mú

''Dirẹba wa ati ẹlọmiran sa asala fun ẹmi wọn, amọ awọn agbebọn naa gba gbogbo owo to wa ni ọwọ wa, ti wọn si gbe wa si ori keke.''

''A kọja omi kan si a si lọ si ori oke, ko to di pe a de ibi ti wọn gbe awọn eniyan miran pamọ si.''

''Ọgọọrọ eniyan lo wa nibẹ, ti mi o si le ka iye wọn, amọ awọn kan sa asala fun ẹmi wọn ko to di pe wọn so wa mọlẹ ki a ma ba a salọ.

''Lẹyin ọjọ keji ni wọn mu wa lọ si ori oke nibi ti ẹrọ ibanisọrọ ti n ṣiṣẹ, ti wọn si pe awọn ẹbi lati bere miliọnu meji meji owo ẹmi lọwọ awọn mọlẹbi mi''

''Fun ọjọ meje ti a lo nibẹ ni wọn n fun wa ni omi idọti lati mu, ti ọplọpọ eniyan si ṣe aisan, amọ omi idọti naa ni wọn yoo tun gbe kana lati fun awọn to n ṣe aisan mu.''

NYSC

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Akunbanirọ naa fikun un pe titi di asiko yii oun ko i tii gbadun ara oun, ti gbogbo iriri yii si ma n wa si ọkan oun ni gbogbo igba, bi oun tilẹ wa ni aarin awọn eniyan.

Bakan naa ni Ajọ NYSC ti gbe awọn agunbanir naa, Lorliam ati Aondona wa si ipinlẹ Benue lati pari agunbanirọ wọn nitori iṣẹlẹ ti wọn la kọja naa.