Sunday Igboho: Ọwọ́ ọlọ́pàá Cotonou tẹ akọ̀royìn tó fi fọ́nran ohùn Sunday Igboho síta

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo fihan pe ọwọ ileesẹ ọlọpaa ni orilẹede olominira Benin ti tẹ akọroyin kan, to n pin fọnran ohun oloye Sunday Igboho kaakiri.
Orukọ akọroyin naa ni Adekunle Aremu, tii se agbohunsafẹfẹ ori redio kan nilu Cotonou.
A gbọ pe ọjọbọ ni awọn ọlọpaa mu Adekunle yọju sile ẹjọ kan nilu naa.
- Bó wù yín, ẹ gbé mi padà sí Nàíjíríà, kò sí nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ - Sunday Igboho
- DSS 20, Sọ́jà 200 àti Babaláwo mẹ́ta ló kọlu ilé Sunday Igboho
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba orílẹ̀-èdè Benin ti gba ibọ̀dè lórí ẹjọ́ Sunday Igboho?
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
- Wo ìgbésẹ tí Sunday Igboho fẹ́ gbé báyìí lórí àwọn agbẹjọ́rò Cotonou tó ní wón ń gba N4m sí N3m lọ́wọ́ òun
- Agbẹnusọ Sunday Igboho ná N2.5m bíí owó oúnjẹ́ lásán, gbas gbos bẹ̀rẹ̀
Iroyin naa ni akọroyin naa lo pe Sunday Igboho lori foonu rẹ, to si bẹrẹ si ka ohun rẹ silẹ lasiko to n ba sọrọ lai sọ fun pe oun yoo se bẹẹ.
Idi ree ti Sunday Igboho se fariga lori isẹlẹ naa, eyi to tu ọpọ asiri nla nla jade, to si pe akọroyin naa lẹjọ lori iwa to hu naa.
Ki ni iha ti agbẹjọro Sunday Igboho ni Cotonou kọ si isẹlẹ yii:
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ yii, agbẹjọro Sunday Igboho ni Cotonou, Ibrahim Salami, ti ohun rẹ wa ninu fọnran naa tun salaye pe oun ni oun n soju Igboho nile ẹjọ lori ọrọ naa.
Salami ni Sunday Igboho gan lo fi ọwọ si iwe ipẹjọ naa lati ẹjọ sun ijọba orilẹede Benin pe oun ko fara mọ igbesẹ ti akọroyin naa gbe.
"Ninu ofin orilẹede Benin, o lodi si ofin lati ka ohun eeyan kan silẹ lai kọkọ sọ fun onitọun tabi gba asẹ lọwọ rẹ lati se bẹẹ́.
Bakan naa, bi akọroyin ọhun se pin fọnran ohun Igboho naa sita tun tako ofin, eyi to mu ki ẹsẹ ti akọroyin naa sẹ di meji."
Lati ọjọ Aje ni awọn ọlọpa nilu Cotonou ti mu akọroyin naa si atimọle, ti wọn si gbe yọju sile ẹjọ lọjọbọ.
Ki ni akọroyin Aremu sọ nile ẹjọ:
Adekunle Aremu sọ niwaju adajọ pe pe foonu oun lo maa n gba ohun ẹni ti oun ba n ba sọrọ silẹ boya oun fẹ bẹẹ tabi tako.
Amọ ile ẹjọ ni irọ nla ni awijare rẹ naa nitori foonu kii se bẹẹ.
Nigba ti wọn bi pe ki lo de to se pin fọnran ohun naa kaakiri fawọn araalu lai naani awọn ọrọ asiri to wa ninu rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Obìrin tó ń ta omi inú ọ̀rá subú pẹ̀lú ọmọ lẹ́yìn torí ebi
- Ẹ ṣì mí gbọ́ ni, a nílò ìrànwọ́ àwọn ìjọba ìpinlẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n - Aregbesola
- Wo orúkọ tuntun tí Facebook yóò má jẹ́ láti àkókò yíì lọ
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí aya aláya lórí Whatsapp
- "Ẹlẹ́wọ̀n Abolongo pa méjì lára ọdẹ ìbílẹ̀ lásìkò tà ń ṣà wọ́n kiri ìgboro Oyo"
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
Adekunle salaye pe ohun fẹ tun nnkan se ni oun fi se bẹẹ amọ adajọ naa ni pe o lu ofin, to si ni ki wọn lọ fi pamọ si ọgba ẹwọn.
Lọwọ lọwọ bayii, akọroyin naa ti n naju lọwọ lọgba ẹwọn ti Sunday Igboho wa nilu Cotonou, ti igbẹjọ rẹ si n tẹsiwaju.
Ọjọ Kejila osu Kọkanla ọdun 2021 ni igbẹjọ afurasi naa yoo tun waye lati mọ iru ijiya sẹ ti adajọ yoo fun akọroyin naa.
Bẹẹ ba gbagbe, a ti mu iroyin wa fun yin saaju nipa fọnran ohun Sunday


















