Facebook yí orúkọ padà sí Meta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ opo ikansiraẹni lori ayelujara, Facebook ti kede orukọ tuntun ti ileeṣẹ naa yoo maa jẹ bayii.
Orukọ tuntun naa ni Meta.
Atunṣe yii lo n waye lasiko ti ileeṣẹ naa n koju oniruru atako lati ọdọ awọn aṣofin orilẹ-ede Amẹrika.
Ninu ipade ita gbangba kan lori ayelujara, oludasilẹ ileeṣẹ ọhun, Mark Zuckerberg sọ pe ileeṣẹ naa yoo tubọ tẹpẹlẹ mọ ohun ti wọn ṣe tẹlẹ atawọn anfani ti awọn eeyan n jẹ lara ileeṣẹ naa kaakiri agbaye.
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí aya aláya lórí Whatsapp
- Gómìnà PDP mẹ́rin lọ fa ojú Mimiko mọ̀ra l'Ondo
- Ilé ẹjọ́ sún ìdájọ́ síwájú lórí ẹjọ́ tí Secondus pè láti dá ìpàdé gbogbogbò ẹgbẹ́ PDP dúró
- Seyi Makinde kò láṣẹ láti fi ẹ̀rọ CCTV sí ọgbà ẹ̀wọ̀n - Aregbesola
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Ṣé lóòtọ́ ni CBN n pín àádọ́ta bílíọnù eNaira lọ́ọ̀fẹ́ fún aráàlú?
- "Ẹlẹ́wọ̀n Abolongo pa méjì lára ọdẹ ìbílẹ̀ lásìkò tà ń ṣà wọ́n kiri ìgboro Oyo"
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
- "Àwa ológun fipá gbàjọba ní Sudan láti dènà ogun abẹ́lé ni"
Zuckerberg ni "Lọwọ yii, o fẹe da bi pe ohun kan ṣoṣo ni awọn eeyan mọ ileeṣẹ wa fun, eyii ti ko ṣafihan awọn oniruru nnkan mii ti an ṣe lọwọ yii, tabi ti a oo ṣe lọjọ iwaju."
Faceboo ni atunto ti awọn n ṣe lọwọ yoo ko gbogbo aapu awọn papọ labẹ orukọ kan ṣoṣo, eyii ti yoo mu ayipada nla ba ileeṣẹ naa.
Ileeṣẹ ọhun tun ṣafihan ami tuntun ti awọn eeyan yoo maa fi da ileeṣẹ naa mọ ni olu ileeṣẹ naa to wa ni Menlo Park, ni California, eyii ti yoo rọpo ami ti awọn eeyan mọ si tẹlẹ to ni awọ buluu.
Zuckerberg sọ pe orukọ tuntun naa tumọ si pe ẹnikẹni to ba fẹ maa lo eyikeyi ninu awọn ohun ti ileeṣẹ naa n ṣe yoo ni lati kọkọ lo oju opo Facebook.
Nnkan bii ọsẹ melo kan sẹyin ni Mark Zuckerberg kọkọ kede pe awọn yoo yi orukọ ileeṣẹ naa pada.
Inu oṣu Keji, ọdun 2004 ni Mark Zuckerberg, Eduardo Saverin, Andrew McCollum, Dustin Moskovitz, ati Chris Hughes da Facebook silẹ nigba ti wọn jọjọ n gbe yara kan gẹgẹ bii akọkọọ ni fasiti Harvard, ni Massachusetss, nilẹ Amẹrika.














