Oyo Jailbreak: Aregbesola ní òun kò kọ̀ ìrànwọ́ CCTV tí Makinde fẹ́ rì sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo

Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Rauf Aregbesola

Minisita fun ọrọ abẹle Ọgbẹni Rauf Aregbesola ti salaye pe oun ko kọ iranwọ ti gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde fẹ se si ọgba ẹwọn Abolongo nilu Oyo.

Aregbesola ni wọn si oun gbọ lori ọrọ naa ni eyi ti wọn ni oun sọ nigba ti oun n kopa lori eto redio kan nilu Ibadan lati ori foonu.

Atẹjade kan ti akọwe feto iroyin rẹ, Sola Fasure fisita lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe awọn ọbayejẹ ẹda kan lo n gbe iroyin ẹlẹjẹ naa kiri nitori ifẹkufẹ ara wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Saaju ni mo ti kọkọ rọ awọn ijọba ipinlẹ lati kọ awọn ile fun awọn afurasi tile ẹjọ ko tii se idajọ wọn nitori ida aadọrin awọn eeyan to wa lọgba ẹwọn lo n reti idajọ lọwọ.

Bakan naa ni mo sọ pe ijọba apapọ yoo mọ riri iranwọ tawọn ijọba ipinlẹ ba se lati sugba aayan to n lọ lọwọ nidi minu agbega bawọn ohun eelo amayedẹrun lawọn ọgba ẹwọn wa.

Àkọlé fídíò, Kiki Osinbajo: T;o bá yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, máa gbìyànjú láti da padà

Amọ o se ni laanu pe awọn ọbayejẹ kan yi ohun ti mo sọ po lati gbe mi kọlu awọn araalu."

Aregbesola wa rọ awọn ijọba ipinlẹ atawọn eeyan ti ọrọ ilẹyii gberu lati ri daju pe agbega ba ilana eto idajọ nilẹ yii atawọn ohun elo to wa lawọn ọgba ẹwọn.

Amin iyasọtọ kan

Seyi Makinde kò láṣẹ láti fi ẹ̀rọ CCTV sí ọgbà ẹ̀wọ̀n - Aregbesola

Seyi Makinde se abẹwo si ọgba ẹwọn Abolongo nilu Oyo

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Minisita fun ọrọ abẹle lorilẹede Naijiria, Ogbeni Rauf Aregbesola ti ni Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ko ni aṣẹ lati fi ẹrọ camera CCTV si ọgba ẹwọn Abolongo ni ipinlẹ Oyo.

Eyi ko ṣẹyin ọrọ ti Gomina Makinde sọ lasiko to ṣe abẹwo si ọgba ẹwọn Abolongo, ti awọn agbebọn ṣekọlu si nipinlẹ naa lọjọ Ẹti.

O kere tan ẹẹdẹgbẹta awọn to wa ni ẹwọn ni wọn sakuro lọgba ẹwọn naa lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Makinde lasiko to ṣabẹwo si ọgba ẹwọn naa ni ijọba oun yoo gbe igbesẹ lati ri pe eto aabo ko mẹhẹ ni awọn ọgba ẹwọn nipinlẹ Oyo.

O ni ijọba yoo pese awọn ohun eelo igbalode fun eto aabo bii CCTV, ki wọn le ma a tọpasẹ iṣẹlẹ to n waye nibẹ.

Àkọlé fídíò, Oyo PDP Crisis: Olopoeyan ní Makinde yá PDP láti dìbò ni, àwọn kò ní gbà kó ba ẹgbẹ jẹ

Amọ, lasiko to n fesi, olubadamọran lori ọrọ iroyin fun Aregbesola, Sola Fasure ni bi o tilẹ ṣe pe inu ire ni gomina Makinde fi sọ ọrọ naa, amọ ko laṣẹ tabi agbara lati ṣe iru nkan to jọ bẹẹ si awọn ọgba ẹwọn.

''Ohun ti Makinde le ṣe ni ki o gba awọn ni imọran nitori ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ abẹle, eleyii ti Aregbesola jẹ minisita rẹ, lo le e pa iru aṣẹ bẹẹ.''

''Bakan naa ni a ti n ṣiṣẹ lati mu idagbasoke ba awọn ọgba ẹwọn kaakiri orilẹede Naijiria, bẹrẹ lati ilu Abuja ati Kano.''

''O ṣe ni laanu pe iṣẹlẹ Abolongo waye ko to di pe atunṣe awọn ọgba ẹwọn de ipinlẹ Ọyọ.''

''Amọ iranwọ ti ijọba ipinlẹ le ṣe to wa ni ikawọ wọn ni lati ri pe awọn to wa ni ọgba ẹwọn ti wọn n duro de idajọ ri idajọ gba ni kiakia.''

''Sunkẹrẹ fakẹrẹ awọn adajọ lori awọn ẹjọ to wa ni ileẹjọ lo fa bi awọn ọgba ẹwọn yii ṣe kun fọfọ, ti ọpọlọpọ wọn si n reti idajọ.

O ni eyi lo fa afunpọ ni awọn ọgba ẹwọn yii, ti awọn agbebọn fi raye ṣekọlu si bẹ.''

''Ijọba apapọ ti bẹrẹ si ni kọ awọn ọgba ẹwọn to lee gba ẹgbẹrun mẹta eniyan lẹẹkan naa ni awọn ẹkun mẹfẹẹfa to wa lorilẹede Naijiria, ti eleyii to wa ni Abuja ati Kano pẹlu ileẹjọ wọn si ti wa ni ṣẹpẹ.''

Àkọlé fídíò, Seyi Makinde: Ẹ̀yin tẹ́ fẹ́ fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sin ba Oyo jẹ́, ẹ ṣọ́ra ṣe

''Ijọba ipinlẹ gbọdọ ran ijọba apapọ lọwọ lati ri pe awọn adajọ wọnyii n da ẹjọ lasiko lai si pe ki wọn ma a sun siwaju ni gbogbo igba, nitori agbara ti wọn ni ni ikawọ niyẹn kii ṣe ki wọn fi CCTV si ọgba ẹwọn.''

Amọ olubadamọran fun Aregbesola naa fikun un pe aba to dara ni gomina Makinde muwa, ti minista naa yoo si gbeyẹwo ni finifini.