Amarachi Nwachukwu: Ibi padà di ire fún olómi ‘Pure Water’ tó dákú, ó bá àánú ńlá pàdé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Obiora Okonkwo
Yoruba ni ori lo n gbe ọla ko ni? Ki Oba oke tete gbe ti wa ko wa.
Bẹẹ lọrọ ri fun arabinrin akuṣẹẹ kan, Amarachi Nwachukwu, ti o n kiri omi inu ọra ti ọpọ mọ si ''pure water'' niluu Okpoko nipinlẹ Anambra.
Ni ọjọ ti Eleduwa yoo sọ ọrọ Amarachi di ayọ lo ṣubu yakata nibi to ti n kiri ''pure water'' toun ti omi lori ati ọmọ lẹyin rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo orúkọ tuntun tí Facebook yóò má jẹ́ láti àkókò yíì lọ
- Asari Dokubo gbéna wojú IPOB pé ìbò gómìnà yóò wáyé ní Anambra
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Seyi Makinde kò láṣẹ láti fi ẹ̀rọ CCTV sí ọgbà ẹ̀wọ̀n - Aregbesola
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí aya aláya lórí Whatsapp
- "Ẹlẹ́wọ̀n Abolongo pa méjì lára ọdẹ ìbílẹ̀ lásìkò tà ń ṣà wọ́n kiri ìgboro Oyo"
- Ṣé lóòtọ́ ni CBN n pín àádọ́ta bílíọnù eNaira lọ́ọ̀fẹ́ fún aráàlú?
- "Àwa ológun fipá gbàjọba ní Sudan láti dènà ogun abẹ́lé ni"
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
- Ọmọ onílẹ̀ mẹ́ta kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn
Aṣe otitọ ni pe atori ọkan ṣekan ni Eleduwa, lasiko ti obinrin yii ṣubu gan an ni oludige ipo gomina ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party, ZLP nipinlẹ Anambra, Dokita Obiora Okonkwo, n ṣe ipolongo ni Okpoko.
Ninu ẹrẹfọ ni Amarachi ṣubu si, nibẹ naa ni Dokita Okonkwo ti pinnu lati foju ara rẹ ri ẹni to ṣubu pẹlu omi lori rẹ.
Amarachi ṣalaye fun oludije fun ipo goimna ẹgbẹ ZLP pe ebi lo jẹ ki oun ṣubu tori oun ko ti jẹun fun ọjọ meji.
''Gaari ni mo mu sun ni bi ọjọ meji sẹyin, o ti rẹ mi, n ko si ni okun lara mọ.
N ko ni ọkọ, igba naira ti ẹnikan bun mi ni mo fi ra ''pure water'' ti mo n kiri ki n le maa ri nkan jẹ,'' Amarachi ṣalaye.
Amọ ayọ ni gbogbo rẹ ja si fun Amarachi lẹyin ti Dokita OKonkwo ra ọunjẹ fun un ti o si tun ṣe iranwọ ẹgbẹrun lọna igba naira fun.
Fada ijọ St. Charles Lwanga ni Dokita Okonwo fun ni N200,000 naa pe ko fun obinrin yii lati fi bẹrẹ owo to ba wuu u.
Oloṣelu Okonkwo kọ lati fun Amarachi gan-an gan-an lowo naa lati le daabo bo o lọwọ awọn janduku to le fẹ gba owo ọhun lọwọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Obiora Okonkwo
Amọ o sọ fun pe ki o lọ gba owo rẹ nile ijọsin lọwọ fada.
Ṣe ẹ mọ pe agba tan laa gba ọlẹ, bi a ba daṣọ fun un, a paa laro.
Oludije ipo gomina fẹgbẹ ZLP tun ṣeleri lati gbe Amarachi lọ si ile iwosan fun ayẹwo ilera rẹ.















