Anambra Governorship Election: Ẹgbẹ́ Biafra tako IPOB lórí ìbò gómìnà Anambra

IPOB

Ẹgbẹ Biafra to yapa, eyi ti Asari Dokubo jẹ adari fun ti ni mimi kan ko lee mi idibo sipo gomina ti yoo waye nipinlẹ Anambra, ni Ọjọ Kẹfa Oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Ẹgbẹ Biafra naa ni bi adari ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu ko ba ti ri idande gba ni ahamọ, eyi ko ni da idibo sipo gomina naa duro.

Adari ikọ iroyin fẹgbẹ naa, Uche Okafor-Mefor wa kilọ fun IPOB lati ti ọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ, ki wọn si fun awọn eniyan ni anfaani lati dibo bo ṣe yẹ labẹ ofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Saanju ni IPOB ti kede pe ki awọn ẹya Igbo joko sile fun ọjọ meje lati fi ẹhonu han pe ki ijọba fi asaaju wọn, Nnamdi Kanu silẹ ni ahamọ DSS.

Wọn ni ti ijọba ko ba fi silẹ, ifẹhonuhan naa yoo bẹrẹ ni Ọjọ Karun un, Oṣu Kọkanla, ọdun 2021 to jẹ alẹ ọjọ to kangun si ọjọ idibo gomina ni ipinlẹ Anambra.

Àkọlé fídíò, Oyo PDP Crisis: Olopoeyan ní Makinde yá PDP láti dìbò ni, àwọn kò ní gbà kó ba ẹgbẹ jẹ

Amọ, ẹgbẹ De facto Biafra Customary Government ti ni aṣẹ IPOB yii tako ẹtọ araalu lati dibo fun ẹni ti wọn fẹ, ti wọn si ni iwa ọdaran ni.

''Idibo sipo gomina yoo waye ni ipinlẹ Anambra nitori ẹgbẹ Biafra gbagbọ ninu idibo tiwantiwa eleyii ti yoo fun awọn eniyan ni anfaani lati dibo yan ẹni ti ọkan wọn fẹ.''

''Nibayii ati ni ọjọ iwaju, ko ni si idiwọ tabi idena fun awọn eniyan lati dibo yan ẹni ti wọn fẹ nitori Biafra ko ni tẹ ẹtọ awọn eniyan mọlẹ.''

''Bakan naa ni a tako igbesẹ IPOB lati maa gbogun ti awọn eniyan pe dandan ki wọn joko sile, eleyii yoo ba igbesẹ iṣejọba ti Biafra n beere fun jẹ, nitori naa a tako igbesẹ yii lati wakati yii lọ.''

Àkọlé fídíò, Kiki Osinbajo: T;o bá yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, máa gbìyànjú láti da padà

''Dida awọn eniyan lagara lati ma le e ṣe ohun to jẹ ẹtọ wọn ko lee bimọ ire fun ohun ti awọn n beere fun ni awujọ.''

Ẹgbẹ De facto Biafra Customary Government fikun un pe, oun ko nilo ipa lati gba ẹtọ ti awọn n bere fun lọwọ ijọba.

O ni igbagbọ oun ni wi pe idibo ni pẹlẹputu lati yan ẹni ti araalu n fẹ, ni ọna abayọ si igbiyanju wọn lati gba ẹtọ wọn lọwọ ijọba apapọ.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn amòfin ní ẹ̀yà Igbo dara pọ̀ mọ́ ẹjọ́ tí àwọn àgbààgbà Àríwá pè lórí Kanu àti IPOB

Awọn ẹgbẹ IPOb

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn agbofinro kan ti wọn jẹ ẹya Igbo ti n rọ ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ nilu Abuja lati jẹ ki wọn dara pọ mọ ẹjọ ti igun kan lẹkun Ariwa pe.

Ẹjọ naa lo da lori bi igun kan ni ariwa naa se n rọ ile ẹjọ lati fun awọn eeyan ẹkun Ila oorun guusu lasẹ lati ya kuro lara Naijiria.

Awọn agbẹjọro naa ni ẹbẹ awọn lo da lori ẹgbẹ IPOB tijọba ti fofin de ati asaaju rẹ, Nnamdi Kanu.

Awọn amofin naa, ti awọn agba amofin Chuks Muoma, Ukpai Ukairo, Ebere Uzoatu ati Obi Emuka n lewaju wọn lo n rọ ile ẹjọ naa lati gba wọn laaye pe ki wọn soju awọn eeyan ẹkun ila oorun guusu Naijiria.

Awọn asofin naa ni ẹjọ ti awọn agbaagba ni ẹkun ariwa Naijiria pe naa lati ni kawọn eeyan ẹkun ila oorun guusu maa lọ, le mu ayipada igbe aye awọn iran ẹya Igbo lọwọ iwaju.

Osu kefa ọdun 2021 ni igun awọn agbaagba lẹkun ariwa naa morile ile ẹjọ pe ko fun awọn olori ile asofin apapọ ni asẹ lati gba ẹya Igbo laaye pe ko kuro nilẹ Naijiria, ki wọn to pari agbeyẹwo ofin ilẹ wa ti wọn n se lọwọ.

Ẹjọ naa si ni awọn oloselu atawọn asaaju ẹkun ariwa ti Nastura Ashir Shariff, Balarabe Rufa'I, Abdul-Aziz Sulaiman ati Aminu Adam lewaju wọn pe.

Awọn olupẹjọ naa ni awọn ko fẹ ki ogun abẹle moran tun sẹlẹ gẹgẹ bo se waye lọdun 1967 si1970 ninu eyi ti ọpọ ẹmi ati dukia olowo iyebiye ba lọ.

Awọn agbẹjọro lati ẹya Igbo naa wa n sọ fun ile ẹjọ pe awọn agbaagba lẹkun ariwa naa ko pe awọn eeyan Igbo ati asoju wọn wọn sinu ẹjọ naa, ki wọn le wa sọ tẹnu wọn.