Tope Alabi ṣe ọjọ́ ìbí, Adeyinka Alaseyori kọrin re kìí

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oniruru ọrọ ikinni lawọn eeyan ti bẹrẹ si n fi ṣọwọ si gbajugbaja olorin ẹmi, Tope Alabi lati sami si ayẹyẹ ọdun mọkanlelaadọta rẹ loke eepẹ.

Lara awọn eeyan jankan to n ṣe ayẹsi Tope Alabi ni Adeyinka Alaseyori to jẹ ki orin "Oniduro" di gbajumọ.

Alaseyori fi ikinni naa ranṣẹ si Tope Alabi loju opo Instagram ati Facebook rẹ.

O ni "Ẹku ayẹyẹ ọjọ ibi yin o maami, ẹ ṣeun ti ẹ gba lati jẹ ohun ti Ọlọrun fẹ ki ẹ jẹ, ayọ yin ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, ẹku oriire naa."

Ti ẹ ko ba gbagbe, ninu oṣu Kẹfa ọdun yii ni fidio kan gbode lori ayelujara, nibi ti Tope Alabi ti n bu ẹnu atẹ lu orin Oniduro, eyii to sọ Alaseyori di gbajumọ olorin ẹmi.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

Ninu fidio ọhun ni Tope Alabi ti sọ pe Ọlọrun kii ṣe oniduro toun.

Tope Alabi sọ siwaju si ninu fidio naa pe ti eeyan ba kọ orin ẹmi, o yẹ ko maa gba imisi lati ọdọ ẹmi mimọ ko to gbe orin jade.

O fikun pe ti akọrin ba tun gba imisi lati ọdọ ẹmi mimọ naa tan, o yẹ ko maa fi ọgbọn ori gbe orin kalẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ọrọ naa bi ọpọ ọmọ Naijiria ninu to bẹẹ ti ọpọ fi n sọ pe ẹtanu lo mu ki irufẹ ọrọ bẹẹ jade lati ẹnu Tope Alabi si olorin to ṣẹṣẹ n bọ lẹyin rẹ.

Lẹyin ti fidio ọhun jade tan ni awọn eeyan bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu Tope Alabi lori ayelujara, paapaa lojo opo Facebook ati Twitter, koda wọn ko jẹ ki oju opo Instagram rẹ sinnmi pẹlu.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo n reti ọrọ ti Alaseyori yoo sọ lori fidio Tope Alabi naa, ọrọ kankan ko jade lẹnu rẹ titi to fi sọ pe bii iya ni Tope Alabi jẹ si oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "Iya wa ni Tope Alabi, bii iya lo si jẹ si gbogbo wa, a si ti di alabukun fun lati inu iṣẹ iranṣẹ rẹ...."

Ẹwẹ, lasiko ti rogbodiyan naa n lọ lọwọ ni ẹni gan to kọkọ gbe orin Oniduro naa jade, Tolulope Adelegan sọrọ soke lori orin ọhun ati igbesẹ to gbe lẹyin ti orin naa sọ Alaseyori di gbajumọ.

Adelegan ṣalaye fun BBC Yoruba pe lootọ, oun lo kọkọ gbe orin naa jade, ṣugbọn ẹmi mimọ lo ni ki oun dakẹ lẹyin ti orin naa sọ Alaseyori di gbajumọ, ti ọpọ si lero pe Alaseyori lo ni orin ọhun.

Àkọlé fídíò, Timi Osukoya: Ọ̀pọ̀ olórin ẹ̀mí ló ń kọrin torí owó tàbí afẹ ayé