Flogging on Altar: Pásítọ̀ na àwọn ọmọ ìjọ láti mọ̀ bí wọn ṣe gbóná fún Ọ́lọ́run

Alufa ati awọn ọmọ ijọ

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Yoruba ni airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bii eeyan ba rin jinaa, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.

Bẹẹ ni ọrọ ri ninu ijọ kan ti ẹnikẹni ko mọ orukọ rẹ, nibi ti olori ijọ naa ti da awọn ọmọ ijọ rẹ kan dubulẹ si ori pẹpẹ, to si n ko bẹliti ya wọn.

Fidio naa to gba ori ayelujara kan lo se afihan pasitọ naa ati pasitọ kekere mii ninu ijọ ọhun, ti wọn n na awọn tọkunrin tobinrin to jẹ ọmọ ijọ wọn, to sun silẹ lori pẹpẹ ni idi.

Gẹgẹ bi ọrọ ti olori ijọ naa se sọ ninu fidio naa, o ni oun n fi bẹliti na wọn lati mọ bi wọn se gbona si, ti wọn si setan fun isẹ iransẹ to wa niwaju wọn.

Awọn ọmọ ijọ naa lo wọ asọ kootu oyinbo dudu ati buluu, ti wọn si doju bolẹ sori pẹpẹ nibi ti wọn sun si.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

Asiko ti awọn pasitọ yii n to ẹgba si ibadi awọn ọmọ ijọ to wa lori pẹpẹ naa, ni awọn ẹgbẹ akọrin ijọ naa n kọ awọn orin pẹlu ohun ilẹ lati se koriya fawọn ọmọ ijọ to n jẹgba naa.

Iyalẹnu lo wa jẹ pe bi awọn pasitọ mejeeji yii se n na awọn ọmọ ijọ naa to, wọn ko pariwo, janpata tabi mira jigi, eyi ti yoo se afihan pe iya ti wọn n jẹ ko ba wọn lara mu.

Awọn araalu faraya lori ayelujara tori bi Pasitọ se n ko bẹliti bo ọmọ ijọ lori pẹpẹ:

Wayi o, awọn araalu ti n fi apa janu lori fidio to jade sita naa, ninu eyi ti pasitọ ti n na awọn ọmọ ijọ lori pẹpẹ.

Ọpọ eeyan to n tara poro lori isẹlẹ naa lo n pariwo pe Ọlọrun ma kuku ku aibinu o.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

Koda awọn miran n beere pe ki ni ka ti se iwa ika tawọn Pasitọ naa n hu sawọn ọmọ ijọ rẹ yii si lasiko yii ta n pariwo tako iwa ika awọn ọlọpaa si araalu.

Awọn miran ni ati Pasitọ to n na eeyan, ati awọn ọmọ ijọ ti wọn n na ni wọn ko ni oye to, ko si yẹ ka huwa ika si ara wa nitori pe a fẹ sin Ọlọrun.