Diezani Alison-Madueke: Ìjọba lu kọ́mú, góòlù àti ilé mínísítà epo rọ̀bì tẹ́lẹ̀ Diezani ní gbàǹjo

Diezani Alison-Madueke:

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ijọba apapọ ti bẹrẹ si lu awọn dukia minisita eporọbi tẹlẹ ni Naijiria, Diezani Alison-Madueke ni gbanjo.

Minisita epo rọbi tẹlẹ ọhun ti n jẹjọ lori ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọ kumọ lasiko ijọba Aarẹ Goodluck Jonathan.

Lara awọn dukia Diezani ti ijọba fẹ ta ni ile awo dami ẹnu to wa ni Banana Island lagbegbe Ikoyi niluu Eko.

Awọn dukia Diezani ti ijọba tun fẹ ta ni goolu olowo iyebiye, aṣọ igbeyawo fun obinrin marunlelọgọfa, kootu mọkanla, kọmu mọkanla, iborun mẹtalelaadọrin.

Awọn nkan mii ni faanu meji, aṣọ bẹẹdi mẹfa ati bata olowo iyebiye mẹrinlelọgọta.

Bakan naa ni ijọba apapọ ti bẹrẹ idiyele dukia olori ileeṣẹ ọmogun ofurufu tẹlẹ ri, Air Chief Marshal Alex Badeh naa.

Ijọba ti kọkọ gbẹsẹ le ile ọgagun Badeh to wa ni Wuse 2 ati Maitama lori ẹsun iwa ajẹbanu lẹnu iṣẹ ọba.

Ni ọsẹ to lọ ni ijọba apapọ bẹrẹ ayẹwo fawọn onimọ nipa dukia tita to le ni ẹgbẹta lati ṣakoso tita awọn dukia tawọn oṣiṣẹ ọba ra lọna eeru.

Ẹgba ọrun

Oríṣun àwòrán, Efcc

Awọn dukia naa to ti di ti ijọba lo wa ni agbegbe mẹẹdọgbọn kaakiri orilẹede Naijiria.

Dukia bii ọkọ, ile, ẹrọ ibaraẹnisọrọ, ẹrọ kọmputa ati awọn nkan mii to jẹ 1,620 ni ijọba apapọ fẹ lu ni gbanjo.

Ipinlẹ Eko ni awọn dukia yii pọ si julọ pẹlu ile mọkanlelọgbọn ati ọkọ 589.

Alaga igbimọ to n ri si tita dukia ti ijọba ti gbẹsẹ le, Mohammed Etsu ṣalaye pe igbimọ naa yoo ri pe abo to muna doko wa lori awọn dukia naa.

Diezani ti wa lorilẹede UK lati ọdun 2015 ti ijọba aarẹ Jonathan pari, lati igba naa si ni ko tii pada si Naijiria.

Ẹwẹ, alaga ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu, Abdulrasheed Bawa, sọ loṣu Karun-un pe biliọnu mẹrinla Naira ni iye ti goolu Diezani to.