Oyo prison break: Ìbúgbàmù ọ̀hún kò mú ẹ̀mí ẹnikẹ́ni lọ

Oyo priosn break

Oríṣun àwòrán, NPS

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ibugbamu mii tun ti waye ni ọgba ẹwọn to wa niluu Abolongo, ni ipinlẹ Oyo.

Ibugbamu ọhun to waye ni ita ọgba ẹwọn naa ko mu ẹmi ẹnikẹni lọ.

Iroyin ni o ṣeeṣe ko jẹ pe ọkan lara awọn ado oloro ti awọn agbebọn to kọlu ọgba ẹwọn naa gbin sibẹ lasiko ikọlu wọn lọjọ Ẹti to kọja lo ṣẹṣẹ bu gbamu.

Ẹwẹ, awọn agbofinro ti ṣabẹwo si ọgba ẹwọn naa lati wo bi nnkan ṣe ri ati ọna ti wọn yoo gba lati yanju ọrọ naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Ẹti to kọja ni awọn agbebọn kan ya bo ọgba ẹwọn naa ni nnkan bii aago mẹwaa aṣalẹ, ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn silẹ.

Ọkan lara awọn ọde ilu naa ṣalaye fun awọn akọroyin pe iye agbebọn to kọlu ọgba ọhun to aadọta, ti oun si mu mẹrin balẹ lara awọn,

Wayi o, wọn ti ri mu pada lara awọn ẹlẹwọn to salọ lasiko ikọlu naa.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa