Farmers-Herders Clash: Darandaran tó fẹ yìnbọn pa olókó rí ẹ̀wọ̀n gbéré he l‘Ekiti

Darandaran ati maalu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ giga kan ni olu ilu ipinlẹ Ekiti, Ado, ti dajọ ẹwọn gbere fun ọkunrin darandaran kan lori ẹsun pe o gbiyanju lati gbẹmi eeyan.

Muhammadu Abubakar ẹni ọdun mejilelọgbọn ni wọn fi ẹsun onipele meji kan pe o fẹ́ gbẹmi eeyan ati pe o ni ohun ija oloro lọwọ.

Wọn fi ẹsun kan pe o gbiyanju lati gbẹmi Oloye Samuel Amaa ati awọn eeyan mii ni Aba Cotonou lọjọ Kẹsan osu Kẹrin ọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọjọ taa n wi yii, wọn ba ibọn ati ọta lọwọ rẹ, eeyan mẹrin si ni olupẹjọ ijọba pe lati wa jẹri tako ọkunrin naa.

Gẹ́gẹ bi agbẹjọro ọlọpaa Taiwo Ajibulu si se sọ, ẹsun yii ni ijiya labẹ ofin Naijiria to lodi si iwa idigunjale.

Ninu ọrọ ti ọkan ninu awọn to wa jẹri nile ẹjọ sọ, ''nigba ti awọn eeyan tako Muhammadu pe ko ma fẹran jẹ ni oko ẹgẹ lo fabinu yọ.

Àkọlé fídíò, Timi Osukoya: Ọ̀pọ̀ olórin ẹ̀mí ló ń kọrin torí owó tàbí afẹ ayé

A gbọ pe o fa ibọn yọ ti o si yinbọn lu awọ́n to wa koju rẹ. Ori lo yọ wọn pe ọta naa ko ba wọn''

Ẹlẹri naa tẹsiwaju pe awọn eeyan suru bo, ti wọn si gba ibọn naa lọwọ rẹ.

''Nigba to n gbiyanju lati salọ ni wọn ri mu, ti wọn si gbe lọ sọdọ ọlọpaa''

Adajọ Adekunle Adeleye nigba to n gbe idajọ kalẹ sọ pe lori ẹsun alakọkọ,''a ran lọ si ẹwọn gbere, lori ẹlẹẹkeji, ẹwọn ọdun mẹwaa la da fun ''

Amin iyasọtọ kan

"Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ yóò tẹ̀síwájú ní Naijiria títí di ọdún tó ń bọ̀"

Food prices in Nigeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwadii kan ti fi han pe ọwọngogo ounjẹ yoo tẹsiwaju ni Naijria titi di ọdun 2022 nitori bi awọn eeyan ṣe n sa fun iṣẹ agbẹ.

Eyii lo n jẹyọ lẹyin ti ileeṣẹ to n ri si iṣiro bi nnkan ṣe n lọ ni Naijiria, NBS, kede loṣu kẹsan an pe irẹsi, ẹyin, elubọ ati tomati ti gbowo lori.

Lọwọ yii, ọpọ ọmọ Naijiria lo n kerora lori iye owo ti wọn n ta apo irẹsi kan, eyii ti iye rẹ ti le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.

NBS tun sọ pe iye owo ti wọn n ta ẹyin naa ti gbowo lori ni nnkan bii ida marundinlọgbọn.

Lawọn agbegbe kan, 342 naira ni wọ n ta kilo tomati kan, to si jẹ pe 286 naira ni wọn n ta ninu oṣu Kẹsan an ọdun yii.

Ni iroyin mii, NBS sọ pe iye owo ti awọn eeyan n wọ ọkọ kaakiri Naijiria naa tun ti gbowo lori, yala ọkọ ofurufu ni o tabi ọkọ ori ilẹ.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

Ninu iwadii ti ajọ United Capital Management ṣe, wọn ni ọwọngogo ounjẹ ti Naijiria n koju lọwọ yii n ṣafihan pe o ṣeeṣe ki ounjẹ tun wọn ju bo ṣe wa yii lọ to ba maa fi di ọdun to n bọ.

Ẹwẹ, ọpọ araalu lo ti n di ẹbi ọwọngogo ounjẹ naa ru ijọba to wa lori alefa nitori eto abo to mẹhẹ.

Pupọ wọn lo n sọ pe ikọlu lemọ-lemọ ti awọn ọdaran Fulani daran-daran n ṣe si awọn agbẹ lo mu ki ọpọ awọn agbẹ fi iṣẹ oko silẹ.

Wayi o, ijọba ti sọ pe oun n gbiyaju lati yanju iṣoro to koju eto abo ati pe adiyẹ oun laagun, ṣugbọn iyẹ ara rẹ ni ko jẹ ki awọn araalu mọ iṣẹ ribiribi to n ṣe.

Àkọlé fídíò, ṣé ẹ lè gbàgbá pé Ajá gidi kọ́ leléyìí tẹ́ẹ bá kòó lọ́nà? Àwọn agbárí tó ṣeé bá BBC sọ̀rọ̀