Cultism: Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn dèrò àtìmọ́lé torí ó fẹ́ da ìdánwò ilé ẹ̀kọ́ rú l'Ogun

Oríṣun àwòrán, ABIMBOLA OYEYEMI,
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan lasiko to n gbiyanju lati da ile ẹkọ ru nigba ti wọn n ṣe idanwo.
Iṣẹlẹ naa wa ye nile ẹkọ imọ ẹrọ ipinlẹ Ogun to wa ni Igbesa, to wa ni Ado Odo, ni ijọba ibilẹ Ota.
Ọwọ tẹ afurasi ọhun lẹyin ti awọn ọlọpaa gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun n mura lati kọlu ile ẹkọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Cotonou tẹ akọ̀royìn tó fi fọ́nran ohùn Sunday Igboho síta
- Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ lórí oyè ẹ̀sìn Grand Mufti Yorùbá tí Oluwo fi Mùsùlùmí kan jẹ
- Obìrin tó ń ta omi inú ọ̀rá subú pẹ̀lú ọmọ lẹ́yìn torí ebi
- Ẹ ṣì mí gbọ́ ni, a nílò ìrànwọ́ àwọn ìjọba ìpinlẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n - Aregbesola
- Wo orúkọ tuntun tí Facebook yóò má jẹ́ láti àkókò yíì lọ
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí aya aláya lórí Whatsapp
- "Ẹlẹ́wọ̀n Abolongo pa méjì lára ọdẹ ìbílẹ̀ lásìkò tà ń ṣà wọ́n kiri ìgboro Oyo"
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
Iroyin ni ede aiyede ti kọkọ waye laarin awọn akẹkọọ kan atawọn alaṣẹ ile ẹkọ naa, eyii to mu ki awọn alaṣẹ ọhun sun idanwo naa to yẹ ko waye ṣaaju siwaju.
Gẹgẹ bii atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi lede, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa gbimọ pọ lati da idanwo naa ru lẹyin ti wọn ko mura lati ṣe idanwo naa ṣaaju.
Oyeyemi sọ pe ni kete ti awọn ọlọpaa gbọ nipa erongba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ni wọn gbera lọ sibẹ pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ NSCDC, to fi mọ ikọ eto abo ile ẹkọ gbogboniṣẹ naa.
Lasiko ti wọn n yẹ awọn akẹkọọ naa wo ki wọn to wa yara idanwo ni akara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa tu sepo.
O ni "Bi ayẹwo ọhun ṣe n lọ lọwọ, a ka apo dudu kan mọ afurasi yi ati omiran ti wọn pe ni Aloma lọwọ, ṣugbọn Aloma fẹsẹ, ti ọwọ si tẹ Ojo Akinola."
"Nigba ti a yẹ inu apo dudu naa wo, a ba ibọn ilewọ atọwọrọ kan ti ọta kan si wa ninu rẹ ninu apo ọhun."
Alukoro ọlọpaa na tẹsiwaju pe "Nigba ti a fi ọrọ wa afurasi naa lẹnu wo, o jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun 'AYE' ni oun, ati pe awọn ẹgbẹ oun wa lati da idanwo naa ru ni."
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ ki wọn gbe ẹjọ naa si ọọfisi ẹka CID fun iwadii ni kikun ati ki wọn le tete ṣawari awọn ọmọ ẹgbẹ naa to na papa bora.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ọlọ́pàá Ogun ń wá akẹ́kọ̀ọ́ tó rán jàndùkú lọ lu àwọn olùkọ́ rẹ̀ lálùbami lọ́gbà ilé ẹ̀kọ́

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dapo Abiodun
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ pe iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ akẹkọọ to ran awọn janduku lọ lu olukọ mejii ni ile ẹkọ Community High School niluu Ijoun, ijọba Ariwa Yewa nipinlẹ Ogun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe awọn akẹkọọ naa n pariwo ni kilaasi wọn nigba ti ọkan lara awọn olukọ ti wọn lu n kọ awọn akẹkọọ mii lọwọ ni kilaasi keji.
Iroyin kan tiẹ sọ pe awọn janduku yii lu awọn olukọ naa debi wi pe wọn di ero ile iwosan.
- Wo àbọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí lórí ilé Kéú tó lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí aṣọ òfì ní Kwara
- Ẹ̀yà tó bá fẹ́ jẹ ààrẹ yóò so mọ́ ẹkùn àríwá - Bakare
- Ṣé lóòtọ́ ni Iskilu Wakili, Balógun Fulani wà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo l'Oyo?
- Ọkọ àti ìyàwó ṣàlàyé ohun tó jẹ́ kí wọ́n ta ọmọ wọn ní N200,000 tí ṣe $500
- Olórí àwọn ọlọ́dẹ Oyo tú iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò bí àádọta agbébọn ṣe kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo
- Agbébọn ya wọ ṣọ́ọ́ṣì lásìkò ìṣọ́ òru l‘Ogun, wọn jí èèyàn mẹ́ta gbé lọ
- “Ẹkùn Àríwá rí sáà ìṣèjọba Buhari bíi àdánù ní wọn ṣe tako pínpín ipò ààrẹ”
''Ariwo tawọn akẹkọo yii n pa lo jẹ ki olukọ yii lọ bawọn wi ni kilaasi wọn.
Lẹyin naa ni akẹkọo yii lọ ran awọn janduku lọ si ile ẹkọ naa ti wọn si lu awọn olukọ yii ati omiran ni alubami.
Kilaasi SS1 ni akẹkọọ yii wa, ileeṣẹ ọlọpaa si ti mọ akẹkọọ naa ṣugbọn iwadii n lọ lọwọ lati fi ọwọ ofin mu akẹkọọ naa.
Ti a ba ti gba akẹkọọ naa mu, o di dandan ki o foju ba ile ẹjọ.
Ẹnikẹni tabi akẹkọọ ki akẹkọọ to ba da ile ẹkọ ru yoo foju ba ile ẹjọ, ileeṣẹ ọlọpaa ko ni gba iru wọn laaye,'' DSP Oyeyemi ṣalaye.
DSP Oyeyemi lo ṣai ṣalaye pe obi to ko awọn janduku lọ sile ẹkọ lati lu olukọ to ba ọmọ rẹ wi ni ile ẹkọ Unity High School, Kajola ni Ibooro ti n foju wina ofin bayii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe awọn mẹta ni awọn ti fi ọwọ ofin mu bayii lori iṣẹlẹ naa ti wọn si n jẹjọ lọwọ.
DSP Oyeyemi tun sọ pe awọn janduku mii tawọn naa ko ada ati oriṣiiriṣii nkan ija oloro lọ lu olukọ nile ẹkọ Baptist College ni Idi -Aba naa ti n jẹjọ bayii.
Awọn eeyan kan tiẹ sọ pe oriṣiiriṣii nkan ija oloro lawọn janduku ọhun lo lati fi lu awọn olukọ naa.













