Gani Adams ṣe ọdún Olókun, ó fi òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ààrẹ Buhari

Aarẹ Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Aareganiadams/Instagram

Aarẹ Ona Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti fi aidunnu rẹ han lori bi ẹnu ibode Nigeria pẹlu Benin, Seme, ṣe ṣi wa ni titi pa.

Adams sọ pe bi ijọba ṣe ti ibode naa pa lati ọdun 2019 jẹ ifiyajẹni fun awọn eniyan Iwọ Oorun Gusu Naijiria, ati akoba fun ọrọ aje.

Oṣu Kọjọ, ọdun 2019 ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti ẹnu ibode naa pa "lati le fi opin si kiko ọja ati nkan ijagun oloro wọ Naijiria".2

Àwọn iròyin tì ẹ le ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọru ni Adams sọ ọrọ yii lasiko to kopa nibi ọdun Olokun to waye ni Suntan Beach, nilu Badagry.

Iba Adams sọ pe titi ibode naa pa fun ọdun mẹta jẹ nkan to buru fun orilẹ-ede bi i Naijiria ati ọrọ aje rẹ.

O ni ijọba sọ pe nitori eto aabo ni oun fi ṣe bẹẹ, ṣugbọn "ko ti i si ayipada rere kankan ninu ipenija eto aabo".

Àkọlé fídíò, Oyo PDP Crisis: Olopoeyan ní Makinde yá PDP láti dìbò ni, àwọn kò ní gbà kó ba ẹgbẹ jẹ

"Lai jẹ pe ogun n waye, titi ibode naa pa jẹ iwa ika si awọn eniyan ilẹ Yoruba. Ipa ti yoo si ni lara ọrọ aje Naijiria paapaa ko ni i kere."

Gani Adams sọ pe oun rọ ijọba Naijiria pe ko tete ṣi ibode Seme pada nitori ipa pataki to n ko ninu idagbasoke ọrọ aje Naijiria ati awọn eniyan rẹ.