South West Governors: Akeredolu ní Tinubu kájúẹ̀ láti ṣe àkóso Nàìjíría

Awọn gomina iwọ oorun gusu Naijiria pẹlu Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Alaga ẹgbẹ awọn Gomina fun ilẹ Yoruba, Rotimi Akeredolu ti sọ pe Asiwaju Bola Tinubu to jẹ agba ọjẹ fẹgbẹ APC koju osunwọn lati dari Naijiria.

Lasiko ti awọn Gomina naa sabẹwo si ile Tinubu to wa ni Bourdillon lo ti sọrọ naa.

Bakan naa lo fi kun pe Tinubu n gbiyanju gẹgẹ bi olori fun ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn oloselu kan jakejado Naijiria ti n kan si Bola Tinubu ti ọpọ n woye pe o fẹ dije dupo aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Amọ titi di ba se n sọrọ yii, Tinubu ko ti fi erongba rẹ han sita lori boya yoo du ipo aarẹ abi bẹẹ kọ.

Awọn Gomina Ekiti, Ogun, Oyo, Eko si lo peju sile Tinubu lasiko abẹwo yii.

Amọ Gomina ipinlẹ Ekiti Kayode Fayemi ko si laarin wọn.

Awọn gomina iwọ oorun gusu Naijiria pẹlu Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Iroyin kan ni Fayemi wa ni Eko lasiko abẹwo yii sugbọn a ko le sọ pato idi ti ko se ba awọn gomina naa lọ sile Tinubu.

Akeredolu, lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni awọn kan si Tinubu to sẹsẹ dari irinajo pada sile lati London ni.

"Ọpọ awa eeyan ẹkun guusu Naijiria la ri asaaju ẹgbẹ APC naa bi ara wa, ta si ni igbagbọ ninu ilana to fi n ṣe asaaju, eyi to fihan pe o n sa ipa rẹ lati dari wa.

Tinubu kii se asaaju fun ilẹ Kaarọ Oojire nikan amọ o tun jẹ asaaju fun ẹgbẹ to n dari Naijiria, APC.

Sugbọn awa eeyan ẹkun iwọ oorun guusu ri gẹgẹ bi asaaju wa."

Bi a ko ba gbagbe awọn Gomina yii, to fi mọ awọn oloselu miran ni Naijiria se abẹwo si Tinubu nigba to wa ni London lẹyin isẹ abẹ lori orunkun rẹ to se nilu ọba.

Akeredolu ko sẹṣẹ maa sọ pe gbọingbọin lawọn Gomina wa lẹyin Tinubu to loun ri gẹgẹ bi ''Kapọ'' ẹgbẹ awọn.

Àkọlé fídíò, Timi Osukoya: Ọ̀pọ̀ olórin ẹ̀mí ló ń kọrin torí owó tàbí afẹ ayé