Naira Marley: Onímọ̀ nípa àyẹ̀wò ní ọ̀pọ̀ nọ́ńbà ike owó ni òun bá nínú fóónù akọrin náà

Oríṣun àwòrán, Naira Marley
Ni ọjọ isẹgun ni igbẹjọ gbajugbaja olorin takasufe nni, Afeez Fasola, ti ọpọ eeyan mọ si Naira Marley tun waye.
Onimọ nipa ayẹwo eroja nilana sayẹsi ti wọn n pe ni Forestic Expert, Augustine Anosike, to n sisẹ pẹlu ajọ EFCC lo wa jẹri nile ẹjọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan akọrin naa.
Bakan naa ni ẹlẹri fun olupẹjọ keji naa tun yọju siwaju adajọ Nicholas Oweibo, tile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni Ikoyi nilu Eko, to n gbọ ẹjọ naa.
- Wo àbọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí lórí ilé Kéú tó lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí aṣọ òfì ní Kwara
- Boko Haram fi tipa fẹ́ mi fún ọkọ àmọ́ ìfẹ́ rẹ̀ gbóná lọ́kàn mi ni ń kò fi sá kúrò
- "Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ yóò tẹ̀síwájú ní Naijiria títí di ọdún tó ń bọ̀"
- Ìfẹ́ ńlá rèé o! Ọmọbabìnrin pàdánù ipò ọlá rẹ̀ láti fẹ́ atàpátadìde ní ọkọ
- Saraki sọ̀rọ̀ lórí bó yá òun lè darapọ̀ APC láti dupò ààrẹ
- Ọkọ àti ìyàwó ṣàlàyé ohun tó jẹ́ kí wọ́n ta ọmọ wọn ní N200,000 tí ṣe $500
- Ọlọ́pàá Ogun ń wá akẹ́kọ̀ọ́ tó rán jàndùkú lọ lu àwọn olùkọ́ rẹ̀ lálùbami lọ́gbà ilé ẹ̀kọ́
- Wo bí o ṣe le ná owó eNaira tí Naijiria fẹ́ ẹ̀ má lò báyìí
- Naijiria yóò dàrú tí ìjọba àpapọ̀ bá le kéde àwọn jàndùkú gẹ́gẹ́ bíi agbésùmọ̀mí - Sheikh Gumi
Anosike salaye fun ile ẹjọ pe awọn ri awọn kaadi ti wọn n na dipo owo gba lọwọ Naira Marley, ti wọn si se ayẹwo awọn atẹjisẹ bii ẹgbẹrun meji, irinwo ati mẹwa ninu foonu rẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, Naira Marley ni ajọ EFCC wọ lọ sile ẹjọ ni ogunjọ, osu Karun-un, ọdun 2019 lori ẹsun oni koko mọkanla, to nii se pẹlu lilẹ idi apo pọ, nini ayederu kaadi owo ati sise magomago.
Amọ Naira Marley ni oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.
Anosike wa sọ fun ile ẹjọ pe iwe ẹri kẹfa ni ibi ti ayẹwo ohun fẹnu ko le lori nipa agbeyẹwo awọn ohun to wa lori foonu iPhone to jẹ ti Naira Marley.
Bakan naa lo tun sọ fun agbẹjọro fun ikọ olupẹjọ, Rotimi Oyedepo, pe foonu igbalode iphone naa lo lagbara lati fi eroja to pọ pamọ.
O fikun pe gbogbo agbeyẹwo awọn lo wa ninu akasilẹ fọnran kan, ti ikọ olupẹjọ si yọ kikida eroja to wulo fun igbẹjọ naa.
Onimọ nipa ayẹwo naa wa rọ ile ẹjọ ati agbẹjọro fun olujẹjọ, Olalekan Ojo SAN lati fi aaye gba ikọ olupẹjọ ko se ayẹwo akasilẹ fọnran naa nile ẹjọ.
Adajọ Oweibo gba ẹbẹ Anosike, ti agbẹjọro Naira Marley naa ko si tako igbesẹ ọhun.
Igbẹjọ naa si n tẹsiwaju lonii, ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu kẹwa ọdun 2021 nibi ti wọn yoo ti safihan awọn ohun to wa ninu fọnran akasilẹ eroja naa nile ẹjọ.














