Sex in the station: Jennifer lóun àti DPO ní ìbálòpọ̀ nínú ọ́fíìsì rẹ̀ àmọ́ òun kò jí ìbọn rẹ̀ gbé

Ọlọpa ilẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFP

Wahala kan ti n rugbo bọ ni agọ ọlọpaa to wa ni Denton laarin awọn ololufẹ meji.

Ọga ọlọpaa Adegoke Akinlade jẹ ọkan ninu awọn ti ọrọ yi ta ba ti ọrẹbinrin rẹ arabinrin Jennifer Madueke si ni ẹnikeji.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ ninu iwe iroyin Naijria Punch, Adegoke ti sọ Madueke si ahamọ lori ẹsun pe o ji ibọn rẹ gbe nigba to sun sinu ọfisi rẹ mọjumọ.

Yatọ si ibọn to ni Jennifer ji, o tun sọ pe owo ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ti oun ko si nu ọfisi, Jennifer ti ji owo yi gbe bakan naa.

Ki wa ni Jennifer sọ si ọrọ yi?

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, Jennifer to ti lo ọjọ mẹta lahamọ ni agọ ọlọpaa Denton ṣaaju ki wọn to gbe lọ si Panti sọ pe oun ko mọ nkankan nipa ibọn to di awati ninu ọfisi Adegoke.

Fakinfa naa tun gba ọna mi yọ pẹlu bi Jennifer ṣe ni ọga ọlọpaa ati oun jijọ ni ibalopọ ninu ọfisi rẹ moju ọjọ Ẹti ti o ni ibọn rẹ sọnu yi.

Wọn ti n ba ọrọ ifẹ wọn bọ ti pẹ

Alaye ti ọga ọlọpaa ṣe fun ileeṣẹ iwe iroyin Punch ni pe ni nkan bi ọdun meje sẹyin ni oun ati Jennifer ti fẹ ara wọn kẹyin ki iṣẹ to gbe oun kuro nilu Eko.

O ni ṣadede lawọn tun pade pada ni nkan bi oṣu kan ati abọ ṣẹyin tawọn si tun gba nọmba ara wọn.

O ni Jennifer bẹrẹ si ni wa si ọfisi oun amọ nigba ti iwa rẹ koba ti oun mu mọ, oun ni ko ma wa mọ.

Ami idamọ ileesẹ ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

A ko ribi Jennifer sọrọ lati fidi ọrọ yi mulẹ amọ lọjọ ti iṣẹlẹ ibọn to sọnu waye, Adegoke ni Jennifer wa ba oun ni ile igbafẹ kan nibi ti oun ati ọrẹbinrin oun miran jijọ n ṣe faaji.

Nigba ti ilẹ ṣu ti o ni oun ati ọrẹbinrin mi lawọn fẹ maa lọ si ile wọn lawọn ko ri ọkọ ti yoo gbe awọn nitori naa ni mo fi ni ki wọn lọ sun ninu ọfisi mi.

Adegoke tẹsiwaju pe oun fi awọn mejeeji silẹ lati lọ ṣe iṣẹ lalẹ ṣugbọn oun pada wa ti oun si fun Jennifer ni owo ọkọ ẹgbẹrun mẹrin.

O ni nigba ti Jennifer lọ tan loun to mọ pe o ji ibọn ati owo gbe ninu ọfisi rẹ.

''Mo pe nọmba rẹ titi ṣugbọn ko gbe. Emi ati arabinrin keji ti wọn jijọ sun ninu ọfisi mi lọ si ọdọ awọn aladura ati alufaa ti wọn si sọ fun wa pe Jennifer lo ji ibọn ati owo mi.Koda mo fun awọn eeyan lowo ki wọn fi bami tọ pinpin ibi to wa.''

O fi kun pe nigba ti ọwọ yoo fi tẹ Jennifer, o jẹwo pe oun mu owo ninu baagi ti mo gbe pamọ ṣugbọn ẹgbẹrun meje loun mu kii ṣe ẹgbẹrun lọna aadọta Naira.

A gbọ pe ọrọ yi ti de etiigbọ Kọmisana ọlọpaa ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ko ti gbe igbesẹ kankan lati fi ni ki ọga ọlọpaa yi lọ rọọkun nile gẹgẹ bi Punch ṣe sọ.

Lọwọlọwọ bayii, agọ ọlọpaa to wa ni Panti ni wọn fi Jennifer si titi di igba ti wọn yoo fi mọ ibi ti ibọn to sọnu yi wa.