Ondo kidnap: Àwọn jàndùkú agbébọn jí èrò ọkọ̀ 18 tó ń lọ sí ìlú Eko láti Ondo lọ

Agbebon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ajinigbe tun ti ṣọṣẹ nipinlẹ Ondo lẹyin ti wọn ji awọn arinrinajo to n lọ si ilu Eko gbe lọ.

Iroyin ni gbogbo awọn to wa ninu ọkọ elero mejilelogun ni wọn jigbe lọ.

Awọn arinrinajo naa ni wọn jigbe ni agbegbe Idoani-Ifira Akoko ni ẹkun ariwa ijọba ipinlẹ Ondo.

Iroyin ni ọkọ naa ni wọn da duro ni agbegbe Idoani-Ifira, nibi ti awọn agbebọn naa ti farapamọ si.

Awọn ti iroyin naa ṣoju wọn sọ pe awọn agbebọn naa bẹrẹ si ni yin ibọn soke lati dẹru ba awọn ara agbegbe naa ati awọn arinrinajo.

Awọn eniyan ni wọn kọkọ gba ohun ini awọn arinrinajo naa, ki wọn to ko wọn wọ inu igbo lọ.

Ninu ọrọ tirẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe Isua Akoko, CSP Hakeem Sadiq ni awọn ọlọpaa kogberegbe pẹlu ajọṣepọ awọn ẹka miran ti wọ igbo lọ lati doola ẹmi awọn eniyan naa.

Nibayii, ọkan lara awọn mọlẹbi awọn ti wọn jigbe sọ pe awọn agbebọn naa tii bere owo ẹmi to to miliọnu mẹwa Naira lọwọ awọn mọlebi, ki wọn to le gba itusilẹ.